مريم

Maryam

Sūrah 19 · ti Mọkkah · āyah 98 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 44

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKāf hā yā ‘aēn sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀ (Ànábì) Zakariyyā.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniZakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A kò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: “Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniYahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ló máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí (tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.)”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan tó jìnnà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: “Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, èmi kò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: “Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan ìyanu ńlá wá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniArábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni tó wà lórí ìtẹ́, tó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ní Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. [1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ìjọ (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) sì yapa-ẹnu (lórí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba l’ọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa![1] Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ òní (ní ilé ayé) wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò dá wọn padà sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBàbá mi, má ṣe bọ aṣ-Ṣaetọ̄n. Dájúdájú aṣ-ṣaetọ̄n jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ aṣ-ṣaetọ̄n (nínú Iná).”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi fún ìgbà kan ná..”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì fi òdodo sórí ahọ́n gbogbo àwọn ènìyàn nìpa wọn (ìyẹn ni pé, gbogbo ìjọ ẹlẹ́sìn ló ń sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn adùn. Láìpẹ́ wọn máa pàdé òfò (nínú Iná).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀[1] fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yẹn. Àti pé Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈnìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn aṣ-ṣaetọ̄n jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ẹni tí ó le jùlọ nínú wọn níbi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí wíwọ inú Iná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀ (àfi kí ó gba ibẹ̀ kọjá). Ó di dandan kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) ló lóore jùlọ ní ibùgbé, ló sì dára jùlọ ní ìjókòó (afẹ́)?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jù wọ́n lọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn tó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún mi nípa ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA ó sì jogún ohun tó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Àwa ń dẹ àwọn aṣ-ṣaetọ̄n sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń gùn wọ́n gan-an (síbi ẹ̀ṣẹ̀)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dàwó lulẹ̀ gbì
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunifún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ tó ń ja òdodo níyàn
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí?