آل عمران

Ali 'Imran

Sūrah 3 · ti Mẹdīnah · āyah 200 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 89

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n jẹ́ ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn.[1] Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.[2] Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà tó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan tó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà[1] -, onípọ́n-na sì ni ìyókù.[2] Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí tó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni tó nímọ̀ pàápàá ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ gan-an ni Ọlọ́rẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa ní irọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: “Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ lọ sí iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀmì kúkú wà fún yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn lójú ogun). Ìjọ kan ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Aláìgbàgbọ́ sì ni ìjọ kejì tí ó ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú.[1] Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùríran.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn ara lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ jaburata àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan tó dára ju ìyẹn lọ fún yín?” Àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún àwọn tó bá bẹ̀rù (Allāhu) ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ̀sìn tó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) kò yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Ẹni tó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: “Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (mùsùlùmí ni wá) fún Allāhu.” Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: “Ṣé ẹ máa gba ’Islām?” Tí wọ́n bá gba ’Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí’Islām), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe déédé àti ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè wọ́n síbi Tírà Allāhu, nítorí kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìndà, tí wọ́n sì ń gbúnrí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: “Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ tó lóǹkà.” Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒ ń mú òru wọnú ọ̀sán.[1] Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru.[2] Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.”[3]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn onígbàgbọ́ òdodo kò gbọ́dọ̀ sọ àwọn aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò (ọ̀rẹ́ finúhannú) lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.[1] Àfi tí ẹ bá ń (fi ọ̀rẹ́ orí ahọ́n) wá ìṣọ́ra lọ́dọ̀ wọn) dáadáa (lórí ìgbàgbọ́ yín).[2] Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò tó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn ẹrúsìn (Rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú ikùn mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n ẹni ẹ̀kọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ̀ sì gba àdúà rẹ̀ ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: “Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?” (Mọryam á) sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIbẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: “Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́-àdúà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): “Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu.[1] (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin.[2] (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” Ó sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” Ó sọ pé: “Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò.[1] Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika [1] sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ẹni iyì ni ní ayé àti ní ọ̀run.[2] Ó sì wà lára àwọn alásùn-únmọ́ (Allāhu).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tó bá dàgbà.[1] Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-’Injīl.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) “Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fún yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú at-Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún yín ní ẹ̀tọ́ fún yín. Mo ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: “Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ wọn pátápátá.[1] Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.[2] Mo sì máa fi àwọn tó tẹ̀lé ọ borí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò jẹ wọ́n níyà líle ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní kíkún. Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni À ń ké fún ọ nínú àwọn āyah àti ìrántí tí ó kún fún òye ìjìnlẹ̀(ìyẹn, al-Ƙur’ān).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, má ṣe wà nínú àwọn oníyèméjì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: “Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣàdúà ìparun (lórí òpùrọ́ nínú wa). Nítorí náà, a óò sọ pé, “ibi dandan (ìgbéjìnnà sí ìkẹ́) Allāhu kí ó máa jẹ́ ti àwọn òpùrọ́.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí, òhun ni ìtàn òdodo. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá sì pẹ̀yìndà (kúrò níbi òdodo), dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan tó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.” [1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi jiyàn nípa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm? A kò sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀ bí kò ṣe lẹ́yìn rẹ̀, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀?[1] Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm kì í ṣe yẹhudi, kì í ṣe nasọ̄rọ̄, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùdúró-déédé, mùsùlùmí. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ènìyàn tó súnmọ́ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jùlọ (nínú ẹ̀sìn ’Islām) ni àwọn tó tẹ̀lé e àti Ànábì yìí - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí). Allāhu ni Alátìlẹ́yìn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIgun kan nínú àwọn onítírà fẹ́ láti ṣì yín lọ́nà. Wọn kò lè ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àfi ara wọn, wọn kò sì fura.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ẹ sì ń jẹ́rìí (sí òdodo rẹ̀)!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì ń fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIgun kan nínú àwọn onítírà wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n tún wí pé:) “Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà (’Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu.” (Wọ́n tún wí pé:) “(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí wọ́n fún yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín.” Sọ pé: “Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) ń fi ìkẹ́ Rẹ̀[1] ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu ni Olóore ńlá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń bẹ nínú àwọn onítírà, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: “Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà.” Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBẹ́ẹ̀ ni (A máa bá wọn wí). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń ta májẹ̀mu Allāhu àti ìbúra wọn ní owó kékeré, àwọn wọ̀nyẹn, kò níí sí ìpín oore kan fún wọn ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Allāhu kò níí bá wọn sọ̀rọ̀, kò sì níí ṣíjú wò wọ́n ní Ọjọ́ Àjíǹde.[1] Kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì ń bẹ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó ń fi ahọ́n wọn yí tírà (Allāhu) padà, nítorí kí ẹ lè lérò pé lára tírà ló wà, kò sì sí lára tírà. Wọ́n sì ń wí pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kò sì wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan nígbà tí Allāhu bá fún un ní tírà, òye ìjìnlẹ̀ àti ipò Ànábì, lẹ́yìn náà kí ó máa sọ fún àwọn ènìyàn pé, “ẹ jẹ́ ẹrúsìn fún mi lẹ́yìn Allāhu.” Ṣùgbọ́n (ó máa sọ pé) “ẹ jẹ́ olùjọ́sìn fún Olúwa (kí ẹ sì máa fi ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kọ́ àwọn ènìyàn) nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tírà àti nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ ẹ̀kọ́ (nípa ẹ̀sìn).”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì[1] pé: “Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí nígbà tí Mo bá fún yín ní tírà àti òye ìjìnlẹ́, lẹ́yìn náà Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yóò dé ba yín; ó máa fi èyí tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹni tí ó bá kẹ̀yìn sí (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lẹ́yìn (àdéhùn) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni Allāhu yó ṣe fi ọ̀nà mọ ìjọ kan tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn? Wọ́n sì jẹ́rìí pé dájúdájú Òjíṣẹ́ náà, òdodo ni. Àwọn ẹ̀rí tó yanjú sì ti dé bá wọn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn ni pé, dájúdájú ègún Allāhu àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) gbogbo àwọn ènìyàn ń bẹ lórí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí lọ́ wọn lára (láti jẹ̀yà nínú Iná).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe, nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n lékún ní àìgbàgbọ́, A ò níí gba ìronúpìwàdà wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùṣìnà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌwọ́ yín kò lè ba oore náà (ìyẹn Ọgbà Ìdẹ̀ra) àyàfi tí ẹ bá ń ná nínú ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ń ná, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo oúnjẹ ló jẹ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àyàfi èyí tí ’Isrọ̄’īl bá ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ṣíwájú kí A tó sọ at-Taorāh kalẹ̀. Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú at-Taorāh wá, kí ẹ sì kà á síta tí ẹ̀yin bá jẹ́ olódodo.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Allāhu sọ òdodo. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah.[1] (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn àmì tó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu? Allāhu sì ni Arínú-róde ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ fi ń ṣẹ́rí ẹni tó gbàgbọ́ lódodo kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí ẹ̀ ń fẹ́ kí ó wọ́,[1] ẹ sì jẹ́rìí (sí òdodo ’Islām)? Allāhu kì í ṣe Onígbàgbé nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé apá kan nínú àwọn tí A fún ní tírà, wọ́n máa da yín padà lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo yín sí ipò aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bẹ̀rù Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ wà ní ipò mùsùlùmí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ dìmọ́ okùn Allāhu (al-Ƙur’ān) ní àpapọ̀, ẹ má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ẹ sì rántí ìkẹ́ Allāhu tí ń bẹ lórí yín (pé) nígbà tí ẹ jẹ́ ọ̀tá (ara yín nígbà àìmọ̀kan), Ó pa ọkàn yín pọ̀ mọ́ra wọn (pẹ̀lú ’Islām), ẹ sì di ọmọ ìyá pẹ̀lú ìkẹ́ Rẹ̀; àti (nígbà tí) ẹ wà létí ọ̀gbun Iná, Ó gbà yín là kúrò nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà (’Islām).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun tó lóore, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe dà bí àwọn tó sọra wọn di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì yapa ẹnu (sí ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn àlàyé tó yanjú ti dé bá wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà ńlá ń bẹ fún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí àwọn ojú kan yóò funfun (fún ìmọ́lẹ̀). Àwọn ojú kan yó sì dúdú. Ní ti àwọn tí ojú wọn dúdú, (A ó bi wọ́n pé:) "Ṣé ẹ ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín ni?" Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ṣàì gbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti àwọn tí ojú wọn funfun (fún ìmọ́lẹ̀), nínú ìkẹ́ Allāhu ni wọn yóò wà. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí kan sí gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jẹ́ ìjọ tó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn,[1] ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bà wọ́n àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba ’Islām) àti àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu ààlà.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn onítírà) kò rí bákan náà. Ìjọ kan tó dúró déédé wà nínú àwọn onítírà, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ gbé. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan (níbi ìyà) lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn tó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ finúhannú kan yàtọ̀ sí ara yín. Wọn kò níí géwọ́ aburú kúrú fún yín. Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó máa kó ìnira ba yín. Ìkórira kúkú ti fojú hàn láti ẹnu wọn. Ohun tí ó sì pamọ́ sínú ọkàn wọn tóbi jùlọ. A ti ṣàlàyé àwọn āyah fún yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onílàákàyè.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn kò sì nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú gbogbo àwọn tírà pátápátá. Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé yín, wọ́n á wí pé: “Àwa gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku àwọn nìkan, wọn yóò máa deyín mọ́ ìka lórí yín ní ti ìbínú. Sọ pé: “Ẹ kú pẹ̀lú ìbínú yín.” Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan bá yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.́
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí o jí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ara ilé rẹ ní ìdájí kùtùkùtù, tí ò ń fi àwọn onígbàgbọ́ òdodo sí àyè ibùjagun, Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí ìjọ méjì nínú yín rò láti ṣojo. Allāhu sì ni Aláfẹ̀yìntì àwọn méjèèjì. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kúkú fún yín ní ìṣẹ́gun ní ogun Badr, nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìlágbára. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRántí nígbà tí ò ń sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo pé: “Ṣé kò níí to yín tí Olúwa yín bá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú àwọn mọlāika, tí Wọ́n máa sọ̀kalẹ̀?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBẹ́ẹ̀ ni (ó máa tó wa.). Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrú, tí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, tí àwọn (ọ̀tá) bá dé ba yín lójijì, Olúwa yín yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún máàrún nínú àwọn mọlāika pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ lára wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kò ṣe é lásán bí kò ṣe kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú fún yín àtí nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe lórí ọ̀tá (láti ibì kan kan) bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu ṣe àrànṣe náà fún yín) nítorí kí Ó lè gé apá kan dànù nínú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tàbí nítorí kí Ó lè dójú tì wọ́n, tí wọ́n sì máa padà wálé lófo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ohun tó kàn ọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. Yálà (Allāhu) máa gba ìronúpìwàdà wọn tàbí Ó máa jẹ wọ́n níyà; dájúdájú alábòsí ni wọ́n.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ó ń foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́, Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Aláàánú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe jẹ èlé, àdìpèlé lórí àdìpèlé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ sì ṣọ́ra fún Iná tí wọ́n ti pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ yára wá àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí ìbú rẹ̀ tó àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí wọ́n pa lésè sílẹ̀ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń ná dúkìá wọn nígbà ìdẹ̀ra àti nígbà ìnira, àwọn tí ń gbé ìbínú mì, àwọn alámòjúúkúrò fún àwọn ènìyàn níbi àṣìṣe; Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni). -
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn ni àforíjìn àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san olùṣe-iṣẹ́ rere sì dára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn orípa kan kúkú ti lọ ṣíwájú yín. Nítorí náà, ẹ rin ilẹ̀ lọ, kí ẹ wòye sí bí ìgbẹ̀yìn àwọn tó pe òdodo nírọ́ ṣe rí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni àlàyé fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti wáàsí sì ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe kọ́lẹ, ẹ má ṣe banújẹ́; ẹ̀yin l’ẹ máa lékè tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ (kèfèrí) náà. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti (nítorí) kí Ó lè sọ àwọn kan nínú yín di òkú ojú-ogun (ní ojú-ọ̀nà Rẹ̀)[1]. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé (ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè ṣàfọ̀mọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè run àwọn aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí Allāhu kò tí ì ṣàfi hàn àwọn tó máa jagun (ẹ̀sìn) nínú yín, tí kò sì tí ì ṣàfi hàn àwọn onísùúrù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ ti ń wá ikú (ogun ẹ̀sìn) ṣíwájú kí ẹ tó pàdé rẹ̀. Ẹ kúkú ti rí i (báyìí), ẹ sì ń wòran.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀.[1] Ṣé tí ó bá kú tàbí tí wọ́n bá pa á, ẹ máa pẹ̀yìndà (sẹ́sìn)? Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (sẹ́sìn) kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu yó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀mí kan kò lè kú àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ikú jẹ́) àkọsílẹ̀ onígbèdéke. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀[1] (ní ayé). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ọ̀run, A máa fún un nínú rẹ̀ (ní ọ̀run). A ó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí wọ́n ti jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún (ọmọ-ẹ̀yìn wọn). Wọn kò ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò kọ́lẹ, wọn kò sì jura wọn sílẹ̀ fún ọ̀tá ẹ̀sìn. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí ohun kan tí wọ́n sọ tayọ pé wọ́n sọ pé: “Olúwa wa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣejù wa nínú ọ̀rọ̀ (àwọn àṣìṣe) wa jìn wá, mú ẹsẹ̀ wa dúró ṣinṣin, kí O sì ṣe àrànṣe fún wa lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Allāhu fún wọn ní ẹ̀san ayé àti dáadáa ẹ̀san ọ̀run. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa yi yín lẹ́sẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Nígbà náà, ẹ máa padà di ẹni òfò (sínú àìgbàgbọ́).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì ni Alárànṣe yín. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn alárànṣe.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA máa fi ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sínú ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́, èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún. Iná ni ibùgbé wọn; ilé àwọn alábòsí sì burú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ti mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún yín nígbà tí ẹ̀ ń pa wọ́n pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, títí di ìgbà tí ẹ fi ṣojo, tí ẹ sì ń jiyàn sí ọ̀rọ̀. Ẹ sì yapa àṣẹ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lẹ́yìn tí Allāhu fi ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí hàn yín. - Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run. - Lẹ́yìn náà, (Allāhu) yí ojú yín kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn nítorí kí Ó lè dan yín wò. Ó sì ti ṣàmójú kúrò fún yín; Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gùnkè sá lọ, tí ẹ̀yin kò sì bojú wo ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn, Òjíṣẹ́ sì ń pè yín láti ẹ̀yìn yín. Nítorí náà, (Allāhu) fi ìbànújẹ́(pípa tí àwọn ọ̀ṣẹbọ pa àwọn kan láààrin yín) san yín ní ẹ̀san ìbànújẹ́ (tí ẹ fi kan Ànábì nípasẹ̀ àìtẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ lójú ogun ’Uhd. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ẹ má baà banújẹ́ lórí ohun tí ó bọ́ fún yín àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fún yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó èrò bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu pátápátá.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí.” Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.”[1] (Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó pẹ̀yìndà nínú yín ní ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé, dájúdájú aṣ-Ṣaetọ̄n l’ó yẹ̀ wọ́n lẹ́sẹ̀ nítorí apá kan ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì kúkú ti ṣàmójú kúrò fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìyá wọn, nígbà tí wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀[1] tàbí (nígbà) tí wọ́n ń jagun, pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wa ni, wọn ìbá tí kú, àti pé wọn ìbá tí pa wọ́n.” (Wọ́n wí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi ìyẹn ṣe àbámọ̀ sínú ọkàn wọn. Allāhu l’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú tí wọ́n bá pa yín sí ojú-ọ̀nà Allāhu tàbí ẹ kú (sínú ilé), dájúdájú àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Allāhu lóore ju ohun tí ẹ̀ ń kójọ (nílé ayé).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú tí ẹ bá kú (sínú ilé) tàbí wọ́n pa yín (s’ójú ogun ẹ̀sìn), dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni wọn máa ko yín jọ sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniPẹ̀lú ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó kúkú fi rọ̀ fún wọn; tí ó bá jẹ́ pé o jẹ́ ẹni burúkú, ọlọ́kàn líle, wọn ìbá ti túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ṣàmójú kúrò fún wọn, bá wọn tọrọ àforíjìn, kí o sì bá wọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀. Tí o bá sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan), kí o gbáralé Allāhu. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbáralé E.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí Allāhu bá ṣe àrànṣe fún yín, kò sí ẹni tí ó máa borí yín. Tí Ó bá sì yẹpẹrẹ yín, ta sì ni ẹni tí ó máa ṣe àrànṣe fún yín lẹ́yìn Rẹ̀? Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá mú nínú ọrọ̀ ogun lọ́nà ìjàǹbá ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹni tí ó (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu dà bí ẹni tí ó padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, ibùgbé rẹ̀ sì ni iná Jahanamọ? Ìkángun náà sì burú.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èkínní kejì èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná ni) wọ́n ní ipò (ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kúkú ti ṣe oore fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí Ó fi lè gbé Òjíṣẹ́ kan dìde sí wọn láààrin ara wọn. (Òjíṣẹ́ náà) ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà (al-Ƙur’ān) àti òye ìjìnlẹ̀ (sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé gbogbo ìgbà tí àdánwò kan bá kàn yín, tí ẹ sì ti fi méjì irú rẹ̀ (kan àwọn kèfèrí), ni ẹ̀yin yóò máa sọ pé: “Ọ̀nà wo ni èyí gbà ṣẹlẹ̀ sí wa?” Sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ ara yín.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ tí ikọ̀ ogun méjèèjì pàdé, (ó ṣẹlẹ̀) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn tó ṣọ̀bẹ-ṣèlu (nínú àwọn mùsùlùmí). (Àwọn onígbàgbọ́ òdodo) sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí á lọ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu tàbí ẹ wá dáàbò bo ẹ̀mí ara yín.” Wọ́n wí pé: “Àwa ìbá mọ ogun-ún jà àwa ìbá tẹ̀le yín.” Wọ́n súnmọ́ àìgbàgbọ́ ju ìgbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó sọ nípa àwọn ọmọ ìyá wọn (tó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn) pé – tí àwọn sì jòkóò kalẹ̀ sílé (ní tiwọn)-, "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n tẹ̀lé tiwa ni, wọn ìbá tí pa wọ́n." Sọ pé: “Ẹ yẹkú dànù fún ẹ̀mí yín tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe lérò pé òkú (ìyà) ni àwọn tí wọ́n pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, bí kò ṣe pé alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń dunnú sí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀. Wọ́n sì ń yọ̀ fún àwọn tí kò tí ì pàdé wọn nínú àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ pé: “Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń bá wọn yọ̀ fún ìkẹ́ àti oore-àjùlọ (tí ń dúró dè wọ́n) lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn onígbàgbọ́ òdodo ráre.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ni) àwọn tó jẹ́pè Allāhu àti Òjíṣẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti f’ara gbọgbẹ́. Ẹ̀san ńlá wà fún àwọn tó ṣe rere, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu) nínú wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ni) àwọn tí àwọn ènìyàn wí fún pé: “Wọ́n mà ti kóra jọ dè yín, nítorí náà ẹ bẹ̀rù wọn.” (Èyí) lékún ìgbàgbọ́ òdodo wọn. Wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó fún wa. Ó sì dára ni Olùgbáralé.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, wọ́n padà délé pẹ̀lú ìkẹ́ àti oore-àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Aburú kan kò sì kàn wọ́n. Àti pé wọ́n (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìyẹn ni aṣ-Ṣaetọ̄n, tí ó ń fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dẹ́rù bà yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Kí ẹ sì bẹ̀rù Mi tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń sáré kó sínú àìgbàgbọ́ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Dájúdájú wọn kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu kò fẹ́ kí ìpín kan nínú oore wà fún wọn ní ọ̀run (ni); ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó fi ìgbàgbọ́ òdodo ra àìgbàgbọ́,[1] wọn kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé bí A ṣe ń lọ́ra fún wọn jẹ́ oore fún wọn. A kàn ń lọ́ra fún wọn nítorí kí wọ́n lè lékún nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kò níí gbé àwọn onígbàgbọ́ òdodo jù sílẹ̀ lórí ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀ (níbi àìmọ onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ṣọ̀bẹ-ṣèlu) títí Ó máa fi ya ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára ẹni dáadáa. Allāhu kò sì níí fi ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ mọ̀ yín, ṣùgbọ́n Allāhu yóò ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Tí ẹ bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ẹ̀san ńlá yó sì wà fún yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àwọn tó ń ṣahun pẹ̀lú ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀ má ṣe lérò pé oore ni fún wọn, bí kò ṣe pé aburú ni fún wọn. A ó fí ohun tí wọ́n fi ṣahun kọ́ wọn lọ́rùn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kúkú ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó wí pé: “Dájúdájú aláìní ni Allāhu, àwa sì ni ọlọ́rọ̀.” A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n wí àti pípa tí wọ́n pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. A sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì síwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ṣàdéhùn fún wa pé a ò gbọdọ̀ gba Òjíṣẹ́ kan gbọ́ títí ó máa fí mú ẹran sàráà kan wá fún wa tí iná (àtọ̀runwá) yóò fi lánu.” Sọ pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín ṣíwájú mi pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí to yanjú àti èyí tí ẹ wí (yìí), nítorí kí ni ẹ fi pa wọ́n tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ ní òpùrọ́. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ìpín-ìpín Tírà àti Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ó máa dan yín wò nínú dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìpalára láti ọ̀dọ̀ àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ tó pọn dandan.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́. Wọ́n sì jù ú sẹ́yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n sì tà á ní owó kékeré. Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń tà mà sì burú (níyà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe lérò pé àwọn tó ń dunnú sí ohun tí wọ́n ṣe (ní àìdáa máa là nínú ìyà). Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí kí àwọn (ènìyàn) máa yìn wọ́n fún ohun tí wọn kò ṣe (níṣẹ́ rere). Nítorí náà, ẹ má ṣe rò wọ́n ro ìgbàlà níbi Ìyà. Ìyà ẹlẹ́ta eléro sì wà fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán; (àmì wà nínú wọn) fún àwọn onílàákàyè.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń rántí Allāhu ní ìnàró, ìjókòó àti ní ìdùbúlẹ̀; tí wọ́n ń ronú sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (wọ́n sì ń sọ pé:) “Olúwa wa, Ìwọ kò ṣẹ̀dàá èyí pẹ̀lú irọ́. Mímọ́ ni fún Ọ. Nítorí náà, ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí O bá mú wọ inú Iná, O ti dójú tì í. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún àwọn alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, dájúdájú àwa gbọ́ olùpèpè kan tó ń pe (ìpè) sí ibi ìgbàgbọ́ pé: “Ẹ gba Olúwa yín gbọ́.” A sì gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, kí O sì pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́, kí O sì pa wá pẹ̀lú àwọn ẹni rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, fún wa ní ohun tí O ṣàdéhùn rẹ̀ fún wa lórí (ahọ́n) àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ. Má sì ṣe dójú tì wá ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Ìwọ kì í yapa àdéhùn.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wọn sì jẹ́pè wọn pé: “Dájúdájú Èmi kò níí fi iṣẹ́ oníṣẹ́ kan nínú yín ráre; ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ara kan náà ni yín (níbi ẹ̀san). Nítorí náà, àwọn tó gbé (ìlú wọn) jù sílẹ̀, tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn, tí wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n ní ojú-ọ̀nà Mi, wọ́n jagun ẹ̀sìn, wọ́n sì pa wọ́n, dájúdájú Èmi yóò bá wọn pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́, Èmi yó sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ẹ̀san dáadáa wà
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe gba ẹ̀tàn pẹ̀lú ìgbòkè-gbodò àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìlú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌgbádùn díẹ̀ (lè wà fún wọn), lẹ́yìn náà iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ibùgbé náà sì burú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ibùdésí kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì lóore jùlọ fún àwọn ẹni rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn onítírà ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún yín àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn; wọ́n ń páyà Allāhu, wọn kì í ta àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu ní owó kékeré. Àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣe sùúrù, ẹ pàrọwà sùúrù, ẹ ṣọ́ bodè ìlú yín (láti lè dènà àwọn ọmọ-ogun ọ̀tá ẹ̀sìn). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.