الدخان

Ad-Dukhan

Sūrah 44 · ti Mọkkah · āyah 59 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 64

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniHā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún.[1] Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSíbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunináà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè tí àwọn ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú tó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí ní òkò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu sọ pé): “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì fi agbami òkun náà sílẹ̀ (ná) kí ó dákẹ́ rọ́rọ́ láì níí ru (kí ojú ọ̀nà tí ẹ tọ̀ nínú rẹ̀ lè wà bẹ́ẹ̀, kí Fir‘aon àti ọmọ-ogun rẹ̀ lè kó sójú-ọ̀nà náà). Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀ (tí a mọ̀ nípa wọn).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé:
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni“Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn tó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú igi zaƙūm
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunini oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ dà bí ògéré epo gbígbóná tí ń hó nínú ikùn
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(tó) dà bí híhó omi tó gbóná gan-an.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán tó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn (sọ̀rọ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, máa retí[1]. Dájúdájú àwọn náà ń retí.