المائدة

Al-Ma'idah

Sūrah 5 · ti Mẹdīnah · āyah 120 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 112

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn[1] ní ẹ̀tọ́ fún yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fún yín (ní èèwọ̀), ẹ má ṣe sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ húrùmí. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (nínú iṣẹ́ hajj). Ẹ má ṣe rú òfin oṣù ọ̀wọ̀, àti ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn tó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-ààlà nítorí pé, wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-ààlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣe é ní èèwọ̀ fún yín ẹran òkúǹbete àti ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tí kì í ṣe “Allāhu” àti ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa àti ẹran tí wọ́n lù pa àti ẹran tí ó ré lulẹ̀ tí ó kú àti ẹran tí wọ́n kàn pa àti èyí tí ẹranko abìjàwàrà jẹ kù àfi èyí tí ẹ bá rí dú (ṣíwájú kí ó tó kú) àti èyí tí wọ́n pa sídìí òrìṣà. Èèwọ̀ sì ni fún yín láti yẹṣẹ́ wò.[1] Ìwọ̀nyẹn ni ìbàjẹ́. Lónìí ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sọ̀rètí nù nípa ẹ̀sìn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi. Mo parí ẹ̀sìn yín fún yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fún yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fún yín. Nítorí náà, ẹni tí ìnira ebi bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀) nínú ebi tó lágbára gan-an, tí kì í ṣe ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ ń wùú dá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[2]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: “Kí ni wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?” Sọ pé: “Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fún yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i[1]. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fún yín.[1] Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fún yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí ’Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí máa bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí máa yàn wọ́n lálè.[2] Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo[3], iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín àti àdéhùn Rẹ̀, èyí tí Ó ba yín ṣe, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e.” Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí déédé nítorí ti Allāhu nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti má ṣe déédé. Ẹ ṣe déédé, òhun l’ó súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ṣe àdéhùn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere (pé) àforíjìn àti ẹ̀san ńlá ń bẹ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ní èrò inú iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín; nígbà tí ìjọ kan gbèrò látinawọ́ ìjà si yín, (Allāhu) sì kó wọn lọ́wọ́ rọ̀ fún yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Àti pé Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì gbé ìjòyè méjìlá dìde nínú wọn. Allāhu sì sọ (fún wọn) pé: “Dájúdájú Mò ń bẹ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá ń kírun, tí ẹ̀ bá ń yọ Zakāh, tí ẹ bá gba àwọn Òjíṣẹ́ Mi gbọ́, tí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́, tí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Dájúdájú Mo máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́. Dájúdájú Mo máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìyẹn nínú yín, ó kúkú ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn ni A fi ṣẹ́bi lé wọn. A sì mú ọkàn wọn le koko (nítorí pé), wọ́n ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínúoore tí A rán wọn létí rẹ̀. O ò níí yé rí oníjàǹbá láààrin wọn àfi díẹ̀ nínú wọn. Nítorí náà, ṣe àmójúkúrò fún wọn, kí o sì foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé lọ́dọ̀ àwọn tó wí pé: “Dájúdájú nasọ̄rọ̄ ni àwa.”, A gba àdéhùn lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A rán wọn létí rẹ̀. Nítorí náà, A dá ọ̀tá àti ọ̀tẹ̀ sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Láìpẹ́ Allāhu máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin onítírà, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti wá ba yín. Ó ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí ẹ fi pamọ́ nínú tírà fún yín. Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀. Ìmọ́lẹ̀ àti Tírà tó yanjú kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Allāhu.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Tírà tó yanjú náà, al-Ƙur’ān), Allāhu ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àwọn n̄ǹkan) tí Allāhu yọ́nú sí, àwọn ọ̀nà àlàáfíà (àwọn ọ̀nà ọlà). Ó sì ń mú wọn jáde láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ó sì ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Sọ pé: “Ta ló ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?” Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ wí pé: “Àwa ni ọmọ Allāhu àti olólùfẹ́ Rẹ̀.” Sọ pé: “Kí ni ìdí tí Ó ṣe ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín nígbà náà?” Rárá (kò rí bí ẹ ṣe wí, àmọ́) abara ni yín nínú àwọn tí Ó ṣẹ̀dá. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin onítírà, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti dé ba yín, tí ó ń ṣe àlàyé (ọ̀rọ̀) fún yín lẹ́yìn àsìkò tí A ti dá àwọn Òjísẹ́ dúró, nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Kò sí oníròó ìdùnnú tàbí olùkìlọ̀ kan tí ó wá bá wa.” Nítorí náà, dájúdájú oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ kan ti wá ba yín. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín, nígbà tí Ó fi àwọn Ànábì sáààrin yín, tí Ó ṣe yín ní ọba, tí Ó tún fún yín ní n̄ǹkan tí kò fún ẹnì kan rí ní àgbáyé (lásìkò tiyín).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ìjọ mi, ẹ wọ orí ilẹ̀ mímọ́ tí Allāhu pa láṣẹ fún yín. Ẹ má se padà sẹ́yìn[1], nítorí kí ẹ má baà padà di ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Mūsā, dájúdájú ìjọ ajẹni-nípá wà nínú ìlú náà. Dájúdájú àwa kò sì níí wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi jáde kúrò nínú rẹ̀. Tí wọ́n bá jáde kúrò nínú rẹ̀, àwa máa wọ inú rẹ̀ nígbà náà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ọkùnrin méjì kan nínú àwọn tí ń páyà (Allāhu) - Allāhu sì kẹ́ àwọn méjèèjì[1] - wọ́n sọ pé: “Ẹ gba ẹnu bodè wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n. Tí ẹ bá wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n, dájúdájú ẹ máa borí wọn. Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ìwọ Mūsā, dájúdájú àwa kò níí wọ inú ìlú náà láéláé níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá sì wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ìwọ àti Olúwa rẹ lọ (síbẹ̀). Kí ẹ̀yin méjèèjì jà wọ́n lógun. Dájúdájú ibí yìí ni àwa yóò jókòó sí ná.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọnú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi rin àrìnnù lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKa ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam méjèèjì fún wọn pẹ̀lú òdodo. (Rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ṣe ọrẹ àsè (láti fi súnmọ́ Allāhu). A gba ti ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì, A kò sì gba ti ìkejì. (Ẹni tí A kò gba tirẹ̀) wí pé: “Dájúdájú èmi yóò pa ọ́.” (Ìkejì) sì sọ pé: “(Ọrẹ àsè) tàwọn olùbẹ̀rù nìkan ni Allāhu máa gbà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú tí o bá na ọwọ́ rẹ sí mi láti pa mí, èmi kò sì níí na ọwọ́ mi sí ọ láti pa ọ́, nítorí pé dájúdáju èmi ń bẹ̀rù Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi fẹ́ kí o padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde) pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ (bí ó ṣe pa) mí àti ẹ̀ṣẹ̀ tìrẹ nítorí kí o lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èrò inú Iná. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ mú ọkàn ara rẹ̀ gírí láti pa arákùnrin rẹ̀. Ó pa á. Ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde, tí ó ń fi ẹsẹ̀ walẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkú[1] arákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: “Tèmí bá mi o! Ṣé mo kágara ni láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí èmi náà sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀?” Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀[1], ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀san àwọn tó ń gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ni pé, kí ẹ pa wọ́n tàbí kí ẹ kàn wọ́n mọ́ igi àgbélébùú tàbí kí ẹ gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn ní ìpasípayọ tàbí kí ẹ lé wọn kúrò nínú ìlú. Ìyẹn ni ìyẹpẹrẹ fún wọn nílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn tó ronú pìwàdà ṣíwájú kí ẹ tó lágbára lórí wọn. Nítorí náà, ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wá àtẹ̀gùn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.[1] Ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá jẹ́ tiwọn àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti fi gba ara wọn sílẹ̀ níbi ìyà Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí gbà á ní ọwọ́ wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sìwà fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò fẹ́ jáde kúrò nínú Iná, wọn kò sì níí lè jáde kúrò nínú rẹ̀. Ìyà gbére sì wà fún wọn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlè lọ́kùnrin àti olè lóbìnrin, ẹ gé ọwọ́ àwọn méjèèjì.[1] (Ó jẹ́) ẹ̀san fún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó sì jẹ́) ìjìyà láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà lẹ́yìn àbòsí (ọwọ́) rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì máa forí jin ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn tó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn tó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” - tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn tó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fún yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fún yín ẹ ṣọ́ra.”[1] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń tẹ́tí gbọ́ irọ́, wọ́n sì ń jẹ n̄ǹkan èèwọ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá wá bá ọ, ṣèdájọ́ láààrin wọn tàbí kí o ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò lè kó ìnira kan kan bá ọ. Tí o bá sì fẹ́ dájọ́, ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn onídéédé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni wọ́n á ṣe fi ọ́ ṣe adájọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé at-Taorāh wà lọ́dọ̀ wọn. Ìdájọ́ Allāhu sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa sọ at-Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn tó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A fún wọn ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ṣe é ní òfin sínú rẹ̀ fún wọn pé dájúdájú ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, imú fún imú, etí fún etí àti eyín fún eyín. Òfin ẹ̀san gbígbà sì wà fún ojú-ọgbẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sí yọ̀ǹda ìgbẹ̀san, ó sì máa jẹ́ pípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA fi ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé orípa wọn (ìyẹn, àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí); tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. A sì fún un ní al-’Injīl. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu ní àsìkò tirẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àwọn tí A fún ní al-’Injīl ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn tó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fún yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fún yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìdájọ́ ìgbà àìmọ̀kan ni wọ́n ń wá ni? Ta ni ẹni tí ó dára ju Allāhu lọ níbi ìdájọ́ fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú (nípa Rẹ̀)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ ní ọ̀rẹ́ àyò. Apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, dájúdájú ó ti di ara wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, o máa rí àwọn tí àárẹ̀ wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa yára lọ sáààrin wọn. Wọn yóò máa wí pé: “À ń bẹ̀rù pé kí àpadàsí ìgbà má baà kàn wá ni.” Ó súnmọ́ kí Allāhu mú ìṣẹ́gun tàbí àṣẹ kan wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Wọn yó sì di alábàámọ̀ lórí ohun tí wọ́n fi pamọ́ sínú ọkàn wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: “Ṣé àwọn (yẹhudi) wọ̀nyí kọ́ ni àwọn tó fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé, dájúdájú àwọn ń bẹ pẹ̀lú ẹ̀yin (onigbàgbọ́ òdodo)?” Iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Nítorí náà, wọ́n sì di ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà níbi ẹ̀sìn rẹ̀ nínú yín, láìpẹ́ Allāhu máa mú àwọn ènìyàn kan wá; Ó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn náà máa nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Wọn yóò rọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọn yó sì le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Wọn yóò máa jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò sì níí bẹ̀rù èébú eléèébú. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbòòrò, Onímọ̀
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nìkan ni ọ̀rẹ́ yín, àwọn tó ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, àwọn sì ni olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá mú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọ̀rẹ́; dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùborí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn tó sọ ẹ̀sìn yín di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe ní ọ̀rẹ́ nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn aláìgbàgbọ́. Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ẹ bá pèpè síbi ìrun kíkí, wọn yóò sọ ọ́ di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ṣe làákàyè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ǹjẹ́ ẹ rí àlèébù kan (ǹjẹ́ ẹ sì kórira kiní kan) lára wa bí kò ṣe pé a gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú àti (igbàgbọ́ wa pé) dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yín ni òbìlẹ̀jẹ́?"
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró nípa èyí tí ó burú ju ìyẹn lọ ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ Allāhu?”[1](Òhun ni ẹ̀san) ẹni tí Allāhu ṣẹ́bilé, tí Ó sì bínú sí, tí Ó sì sọ àwọn kan nínú wọn di ọ̀bọ àti ẹlẹ́dẹ̀ àti (ẹ̀san) ẹni tí ó ń bọ àwọn n̄ǹkan kan, tí wọn kò pe ara wọn ní ọlọ́hun, tí wọn kò sì yọ̀nù sí bí ẹ ṣe sọ wọ́n di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Àwọn wọ̀nyẹn ni ipò wọn burú jùlọ, àwọn sì ni wọ́n ṣìnà jùlọ kúrò lójú-ọ̀nà tààrà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Dájúdájú wọ́n wọlé (tì yín) pẹ̀lú àìgbàgbọ́, wọ́n sì ti jáde pẹ̀lú rẹ̀. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniO máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń yára kó sínú ẹ̀ṣẹ̀, ìtayọ ẹnu-ààlà àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni kò jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn máa kọ̀ fún wọn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú! Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn yẹhudi wí pé: “Ọwọ́ Allāhu wà ní dídì pa.” A di ọwọ́ wọn pa. A sì ṣẹ́bi lé wọn nítorí ohun tí wọ́n wí. Ọ̀rọ̀ kò rí bí wọ́n ṣe sọ ọ́ bí kò ṣe pé, ọwọ́ Rẹ̀ méjèèjì wà ní títẹ́ sílẹ̀. Ó sì ń tọrẹ bí Ó ṣe fẹ́. Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ̀ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìtayọ ẹnu ààlà àti àìgbàgbọ́ ni. A sì ju ọ̀tá àti ìkórira sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá dáná ogun, Allāhu sì máa paná rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn onítírà gbàgbọ́ ní òdodo, kí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), Àwa ìbá pa àwọn àìda wọn rẹ́ fún wọn, Àwa ìbá sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn (ìyẹn, al-Ƙur’ān), wọn ìbá máa jẹ láti òkè wọn àti láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn. Ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó dúró déédé, (àmọ́) ohun tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ń ṣe níṣẹ́ burú.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ Òjíṣẹ́, kéde gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Tí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (àwọn tí wọn kò fẹ́ mọ̀nà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi, - àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄, - ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣiṣẹ́ rere, kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kúkú gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì rán àwọn Òjíṣẹ́ kan sí wọn. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ kan bá dé bá wọn pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí wọn kò fẹ́, wọ́n pe igun kan ní òpùrọ́, wọ́n sì ń pa igun kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì lérò pé kò níí sí ìfòòró;[1] wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití (sí òdodo). Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́jú, wọ́n tún dití (sí òdodo); ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn (ló ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu, Òun ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Mọsīh sì sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Ìkẹta (àwọn) mẹ́ta.” Kò sì sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Tí wọn kò bá jáwọ́ níbi ohun tí wọ́n ń wí, dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro l’ó máa jẹ àwọn tó di kèfèrí nínú wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣé wọn kò níí ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, kí wọ́n sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni Mọsīh bí kò ṣe Òjíṣẹ́ kan. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Olódodo sì ni ìyá rẹ̀. Àwọn méjèèjì máa ń jẹ oúnjẹ. Wo bí A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún wọn. Lẹ́yìn náà, wo bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò ní ìkápá ìnira àti àǹfààní kan fún yín? Allāhu, Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, (ẹ má sọ ohun tí) kì í ṣe òdodo. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú ìjọ kan tó ti ṣìnà ṣíwájú (ìyẹn, àwọn yẹhudi). Wọ́n ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Wọ́n sì ṣìnà kúrò ní ojú ọ̀nà tààrà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣẹ́bi lé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí ahọ́n (Ànábì) Dāwūd àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-ààlà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kì í kọ ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ láààrin ara wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì burú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniO máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn tó ń bá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣọ̀rẹ́. Ohun tí ẹ̀mí wọn tì síwájú fún wọn sì burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Allāhu fi bínú sí wọn. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Ìyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, wọn kò níí mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú o máa rí i pé àwọn ènìyàn tí ọ̀tá wọn le jùlọ sí àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ni àwọn yẹhudi àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Dájúdájú o sì máa rí i pé àwọn ènìyàn tó súnmọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo jùlọ ní ìfẹ́ ni àwọn tó wí pé: “Dájúdájú nasọ̄rọ̄ ni àwa.” Ìyẹn nítorí pé àwọn àlùfáà àti olùfọkànsìn ń bẹ láààrin wọn. Àti pé dájúdáju wọn kò níí ṣègbéraga (sí òdodo).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ náà, o máa rí ẹyinjú wọn tí ó máa damije nítorí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nínú òdodo. Wọ́n á sì sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo, kọ wá mọ́ ara àwọn olùjẹ́rìí (òdodo).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ tí a ò fi níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí ó dé bá wa nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān), tí a sì ń jẹ̀rankàn pé kí Olúwa wa fi wá sínú àwọn ẹni-ire.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, nítorí ohun tí wọ́n sọ, Allāhu san wọ́n ní ẹ̀san pẹ̀lú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún àwọn olùṣe-rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe sọ àwọn n̄ǹkan dáadáa tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún yín di èèwọ̀. Ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jẹ n̄ǹkan ẹ̀tọ́ tó dára nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín. Àti pé ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kò níí fí ìbúra tí ó bọ́ lẹ́nu yín bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi àwọn ìbúra tí ẹ fínnúfíndọ̀ mú wá bi yín. Nítorí náà, ìtánràn rẹ̀ ni bíbọ́ tálíkà mẹ́wàá pẹ̀lú oúnjẹ tí ó wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí ẹ̀ ń fi bọ́ ará ilé yín, tàbí kí ẹ raṣọ fún wọn, tàbí kí ẹ tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (èyí ṣe), ó máa gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni ìtánràn ìbúra yín nígbà tí ẹ bá búra. Ẹ ṣọ́ ìbúra yín. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí,[1] tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò[2], ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ aṣ-Ṣaetọ̄n ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí aṣ-Ṣaetọ̄n ń fẹ́ ni pé ó máa dá ọ̀tá àti ìkórira sílẹ̀ láààrin yín níbi ọtí àti tẹ́tẹ́. Ó sì fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi ìrántí Allāhu àti níbi ìrun kíkí. Ṣé ẹ̀yin kò níí jáwọ́ (níbi iṣẹ́aṣ-Ṣaetọ̄n) ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ tẹ̀lé ti Allāhu, ẹ tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Kí ẹ sì ṣọ́ra. Nítorí náà, tí ẹ bá gbúnrí, kí ẹ mọ̀ pé ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere nípa ohun tí wọ́n jẹ (nínú ouńjẹ ṣíwájú òfin) nígbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ́rù Allāhu, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú Allāhu yóò fi kiní kan dan yín wò níbi ẹran-ìgbẹ́ tí ọwọ́ yín àti ọ̀kọ̀ yín bà (nínú aṣọ hurumi) nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni tó ń páyà Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah)[1]. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ẹ̀san rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l’ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó máa jẹ́) ẹran ọrẹ tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí kí ó fi ààwẹ̀ dípò ìyẹn, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun tó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ húrùmí tàbí nínú húrùmí), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣe odò dídẹ àti jíjẹ oúnjẹ (òkúǹbete) inú rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún yín. Ó jẹ́ n̄ǹkan ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn onírìn-àjò. Wọ́n sì ṣe ìgbẹ́ dídẹ ní èèwọ̀ fún yín nígbà tí ẹ bá wà ní nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọ́n máa ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ṣe Kaabah Ilé Ọ̀wọ̀ ní ibùdúró ṣẹ̀sìn fún àwọn ènìyàn. (N̄ǹkan ààbò náà ni) àwọn oṣù ọ̀wọ̀, àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ náà bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn). Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ohun burúkú àti ohun dáadáa kò dọ́gba, púpọ̀ ohun burúkú ìbáà jọ ọ́ lójú”. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè, nítorí kí ẹ lè jèrè.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe máa bèèrè nípa àwọn n̄ǹkan sá. Tí A bá fi hàn yín, ó máa kó ìpalára ba yín. Tí ẹ bá sì bèèrè nípa (àwọn n̄ǹkan tó yẹ láti bèèrè nípa ẹ̀sìn) nígbà tí À ń sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ lọ́wọ́, A máa fi hàn yín. Allāhu ti ṣe àmójúkúrò nípa rẹ̀. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ kan kúkú ti bèèrè rẹ̀ ṣíwájú yín. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kò fi ẹran bahīrah, ẹran sā’ibah, ẹran wasīlah àti ẹran hām lọ́lẹ̀.[1] Ṣùgbọ́n àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. (Ẹ máa bọ̀ wá) sí ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ náà.”[1] Wọ́n á wí pé: “Ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ti tó wa.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀nà. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Nígbà náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, (ẹ wá) ẹ̀rí jíjẹ́ láààrin yín nígbà tí (ìpọ́kàkà) ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín tí ó fẹ́ sọ àsọọ́lẹ̀. (Ẹ wá) onídéédé méjì nínú yín.[1] Tàbí àwọn méjì mìíràn yàtọ̀ si yín tí ẹ̀yin bá wà lórí ìrìn-àjò tí àjálù ikú bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ si yín.[2] Ẹ dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ìrun, kí wọ́n fi Allāhu búra, tí ẹ bá ṣeyèméjì (sí òdodo wọn, kí wọ́n sì sọ pé:) “A ò níí ta ìbúra wa ní iye kan kan, kódà kó jẹ́ ẹbí. A ò sì níí fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí Allāhu (pa láṣẹ) pamọ́. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú àwa wà nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá sì mọ̀ pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà tàbí jíjí dúkìá aláìsí), kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí àsọọ́lẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sì jùlọ,[1] (ìyẹn) ènìyàn méjì tí ó súnmọ́ òkú jùlọ rọ́pò àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ (níbi mímú àsọọ́lẹ̀ mìíràn wá fún òkú). Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: “Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-ààlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù (ìbúra ẹni méjì àkọ́kọ́) lẹ́yìn ìbúra tiwọn (ìbúrà ẹni méjì kejì). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí Allāhu yóò kó àwọn Òjíṣẹ́ jọ, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni èsì tí wọ́n fún yín?” Wọ́n á sọ pé: “Kò sí ìmọ̀ kan fún wa (nípa rẹ̀). Dájúdájú Ìwọ nìkan ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-’Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo dí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ fún ọ,[1] nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Mo fi mọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ[1] nínú ọkàn wọn pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Èmi àti Òjíṣẹ́ Mi. Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ǹjẹ́ Olúwa rẹ lè sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti sánmọ̀?” Ó sọ pé: “Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “A fẹ́ jẹ nínú rẹ̀, a sì fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, kí á sì lè mọ̀ pé o ti sọ òdodo fún wa. A sì máa wà nínú àwọn olùjẹ́rìí.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: “Allāhu, Olúwa wa, sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti inú sánmọ̀, kí ó jẹ́ ọdún fún ẹni àkọ́kọ́ wa àti ẹni ìkẹ́yìn wa.[1] Kí ó sì jẹ́ àmì kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Pèsè fún wa, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.”[2]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sọ pé: “Dájúdájú Èmi yóò sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn náà nínú yín, dájúdájú Mo máa jẹ ẹ́ níyà kan tí Mi ò fi jẹ ẹnì kan rí nínú gbogbo ẹ̀dá.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l’o sọ fún àwọn ènìyàn pé: “Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?” Ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. Èmi ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sọ ohun kan fún wọn bí kò ṣe ohun tí O pa mí láṣẹ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín.” Mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn níwọ̀n ìgbà tí mò ń bẹ láààrin wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí O gbà mí kúrò lọ́wọ́ wọn, Ìwọ ni Olùṣọ́ lórí wọn. Ìwọ sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí O bá jẹ wọ́n níyà, dájúdájú ẹrú Rẹ ni wọ́n. Tí O bá sì forí jìn wọ́n, dájúdájú Ìwọ nìkan ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ tí òdodo àwọn olódodo yóò ṣe wọ́n ní àǹfààní. Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú wọn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.