الصف
As-Saf
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí kí ni ẹ ṣe ń sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe níṣẹ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ jẹ́ ohun ìbínú tó tóbi ní ọ̀dọ̀ Allāhu pé kí ẹ sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn tó ń jagun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀ (tí wọ́n tò ní) ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ẹni pé ilé tí wọ́n lẹ̀pọ̀ mọ́ra wọn ni wọ́n
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ óò ṣe fi ìnira kàn mí. Ẹ sì kúkú mọ̀ pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni èmi jẹ́ si yín.” Nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ (kúrò níbi òdodo), Allāhu yẹ ọkàn wọn. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd.”[1] Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, wọ́n á wí pé: “Idán pọ́nńbélé ni èyí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTa sì ni ó ṣàbòsí tó tayọ ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tí wọ́n sì ń pè é sínú ’Islām! Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń gbèrò láti fi (ọ̀rọ̀) ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ Allāhu. Allāhu yó sì mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn kárí, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun tó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa (ẹ̀sìn) Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: “Àwa ni alárànṣe (fún ẹ̀sìn) Allāhu.” Igun kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn tó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí.[1]