التغابن

At-Taghabun

Sūrah 64 · ti Mẹdīnah · āyah 18 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 108

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu. TiRẹ̀ ni ìjọba. TiRẹ̀ sì ni ẹyìn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Aláìgbàgbọ́ wà nínú yín. Onígbàgbọ́ òdodo sì wà nínú yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ya àwòrán yín. Ó sì ṣe àwọn àwòrán yín dáradára. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìró àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìṣáájú kò tí ì dé ba yín ni? Nítorí náà, wọ́n tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé abara l’ó máa fi ọ̀nà mọ̀ wá?” Nítorí náà, wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì pẹ̀yìndà (sí òdodo). Allāhu sì rọrọ̀ láì sí àwọn. Àti pé Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fún yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ tí A sọ̀kalẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù.[1] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀdánwò kan kò lè ṣẹlẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, Allāhu máa fi ọkàn rẹ̀ mọ̀nà.[1] Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá gbúnrí, ìkede ẹ̀sìn tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọ̀tá wà fún yín nínú àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún wọn. Tí ẹ bá ṣàmójúkúrò, tí ẹ ṣàfojúfò, tí ẹ sì ṣàforíjìn (fún wọn), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín. Allāhu sì ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e, kí ẹ sì náwó (fún ẹ̀sìn Rẹ̀) lóore jùlọ fún ẹ̀mí yín. Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ bá yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́pẹ́[1], Aláfaradà,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOnímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.