التكاثر
At-Takathur
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí ẹ fi wọ inú sàréè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ní ti òdodo, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti òdodo, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa fi ojú rí i ní àrídájú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).