القارعة

Al-Qari'ah

Sūrah 101 · ti Mọkkah · āyah 11 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 30

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀkókò ìjáyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni Àkókò ìjáyà?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunió sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniHāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òhun ni) Iná gbígbóná tó ń jó gan-an.