الهمزة

Al-Humazah

Sūrah 104 · ti Mọkkah · āyah 9 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 32

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunièyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).