الفيل

Al-Fil

Sūrah 105 · ti Mọkkah · āyah 5 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 19

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kò sọ ète wọn di òfo àti anù bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (tó ti gbaná sára).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì sọ wọ́n di bíi pòpórò gbígbẹ tí ẹranko jẹ lájẹdàsílẹ̀.