الحجر
Al-Hijr
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣeé ṣe kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ìwọ tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn náà ni A ṣe máa fi (àìsàn pípe al-Ƙur'ān nírọ́) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (nínú ìjọ tìrẹ náà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí gbà á gbọ́; ìṣe (Allāhu[1] lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀),
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kan fi n̄ǹkan bo ojú wa ni. Rárá, ènìyàn tí wọ́n ń dan ni àwa sẹ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kúkú fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀ (ayé). A ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ṣọ́ ọ kúrò lọ́dọ̀ gbogbo ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi (ṣaetọ̄n) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniIlẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A rán àwọn atẹ́gùn láti kó àwọn ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fún yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa, Àwa ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí Mo bá ṣe é tó gún régétán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni náà.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “’Iblīs, kí ló dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ wí pé: “Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ tí wọ́n máa gbé ẹ̀dá dìde.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ wí pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàfi àwọn ẹrúsìn Rẹ nínú wọn, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Mi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn tó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fún yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra;[1] dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìṣìnà àti àìmọ̀kan wọn, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ará ’Aekah[1] náà jẹ́ alábòsí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì ló kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò tó rẹwà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān Ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ méjèèjì wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé fún oríṣiríṣi àwọn kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn tó ń pín òdodo mọ́ irọ́;
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín,[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ.[1] Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniJọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ.