النحل
An-Nahl
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn (fún yín). Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fún yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀ṣọ́ tún ń bẹ fún yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín tó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ kò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ kò mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀)[1]. Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tó ń sọ omi kalẹ̀ (fún yín) láti sánmọ̀. Mímu wà fún yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀, tí ẹ fi ń bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fún yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fún yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó rọ odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - o sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ - àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn oore àjùlọ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má baà mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀;
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.[1] Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò jí wọn dìde (nínú sàréè).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó látibi àwọn òpó ilé. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde (Allāhu) yóò yẹpẹrẹ wọn. Ó sì máa sọ pé: “Ibo ni àwọn (tí ẹ sọ di) akẹgbẹ́ Mi wà, àwọn tí ẹ tìtorí wọn yapa (ọ̀rọ̀ Mi)?” Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ẹ̀sìn yó sì sọ pé: “Dájúdájú àbùkù àti aburú ọjọ́ òní wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Bẹ́ẹ̀ ni (irọ́ lẹ́pa)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà Iná lọ, olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Rere ni.” Rere ti wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn lóore jùlọ. Àti pé dájúdájú ilé àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) dára.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra 'Adn ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí mọlāika ń pa, nígbà tí wọ́n ń ṣe rere lọ́wọ́, (àwọn mọlāika) ń sọ pé: “Àlàáfíà fún yín. Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́ yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fẹ́ ni àwa ìbá tí jọ́sìn fún kiní kan lẹ́yìn Rẹ̀, àwa àti àwọn bàbá wa. Bákàn náà, àwa ìbá tí ṣe kiní kan ní èèwọ̀ lẹ́yìn Rẹ̀.” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Ǹjẹ́ ojúṣe kan wà fún àwọn Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn tó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí o bá ń ṣojú kòkòrò sí ìmọ̀nà wọn, dájúdájú Allāhu, ẹni tí Ó bá ṣì lọ́nà, kò níí mọ̀nà,[1] kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan kan fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Allāhu kò níí gbé ẹni tí ó kú dìde.” Bẹ́ẹ̀ ni, (àjíǹde jẹ́) àdéhùn òdodo lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu yóò gbé ẹ̀dá dìde) nítorí kí Ó lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí fún wọn àti nítorí kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lè mọ̀ pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀rọ̀ Wa fún kiní kan nígbà tí A bá gbèrò rẹ̀ ni pé, A máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ti Allāhu, lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti ṣàbòsí sí wọn, dájúdájú Àwa yóò wá ibùgbé rere fún wọn. Ẹ̀san Ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé (àwọn tí kò ṣe hijrah) mọ̀ ni.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù, wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(A fi) àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn[1] àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àwọn tó dá ète aburú fi ọkàn balẹ̀ pé Allāhu kò lè mú ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ni, tàbí pé ìyà kò lè dé bá wọn láti àyè tí wọn kò ti níí fura?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí (Allāhu) kò lè gbá wọn mú lórí ìrìnkè-rindò wọn ni? Wọn kò sì níí mórí bọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú díẹ̀díẹ̀ ni?[1] Nítorí náà, dájúdájú Olúwa yin má ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ṣé wọn kò wòye sí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì[1] tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ní n̄ǹkan abẹ̀mí àti àwọn mọlāika ń forí kanlẹ̀ fún. Wọn kò sì ṣègbéraga.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń páyà Olúwa wọn tó ń bẹ lókè wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sọ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ọlọ́hun méjì. Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nítorí náà, Èmi (nìkan) ni kí ẹ bẹ̀rù.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTiRẹ̀ sì ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. TiRẹ̀ sì ni (àfọ̀mọ́) ẹ̀sìn títí láéláé[1] Nítorí náà, ṣé (n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí Allāhu ni ẹ̀yin yóò máa bẹ̀rù ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tí ẹ ní nínú ìdẹ̀ra, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Lẹ́yìn náà, tí ọwọ́ ìnira bá tẹ̀ yín, Òun ni ẹ̀ ń ké pè (fún ìdáǹdè.)
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá mú ìnira náà kúrò fún yín tán, nígbà náà ni apá kan nínú yín yó sì máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn. Nítorí náà, ẹ máa gbádùn ǹsó. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò nímọ̀ nípa rẹ̀.[1] Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). - Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá fún ọ̀kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú (pé ó bí) ọmọbìnrin, ojú rẹ̀ yóò di dúdú fún ìbànújẹ́, tí ó sì máa pa á mọ́ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì máa fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ìró aburú tí wọ́n fún un. Ṣé ó máa gbà a mú ní n̄ǹkan àbùkù ni tàbí ó máa bò ó mọ́lẹ̀ láàyè? Ẹ gbọ́, ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTi àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni àkàwé aburú. Ti Allāhu sì ni àkàwé tó ga jùlọ. Àti pé Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń gbá àwọn ènìyàn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn, ìbá tí ṣẹ́ abẹ̀mí kan kan kù sórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí lè sún un sẹ́yìn di àkókò kan, wọn kò sì níí lè sún un síwájú.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń fi (ọmọbìnrin) - n̄ǹkan tí wọn kórira - lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi ara Rẹ̀ búra,[1] dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, aṣ-Ṣaetọ̄n ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn ní òní. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí;[1] ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì ń fi jí ilẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fún yín mu nínú n̄ǹkan tó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ tó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn tó ń mu ún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé láti ara àwọn èso dàbínù àti èso àjàrà ni ẹ ti ń ṣe ọtí[1] àti n̄ǹkan jíjẹ-mímu tó dára. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ sì fi mọ kòkòrò oyin pé: “Mu ilé sínú àpáta, (mú un sínú) igi, (kí ó sì mú un) sínú ohun tí (àwọn ènìyàn) mọ ga.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, jẹ lára gbogbo èso, kí o sì tọ àwọn ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ìtẹríba.” Ohun mímu tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn yóò máa jáde láti inú kòkòrò oyin. Ìwòsàn wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó ṣẹ̀dá yín. Lẹ́yìn náà, Ó ń gba ẹ̀mí yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá padà sí ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alágbára.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Bẹ́ẹ̀, àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, wọn kì í fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, nítorí kí wọ́n má baà wà ní dọ́gban̄dọ́gba pẹ̀lú wọn níbi arísìkí![1] Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fún yín láti ara yín. Ó fún yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yó sì máa ṣàì moore sí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn aláfijọ kan lélẹ̀ pé wọ́n jọ Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí tó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí?[1] Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà?[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀rọ̀ Àkókò náà kò kúkú tayọ ìṣẹ́jú tàbí kí ó tún súnmọ́ julọ. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò wòye sí àwọn ẹyẹ tí A rọ̀ (fún fífò) nínú òfurufú (lábẹ́) sánmọ̀? Kò sí ẹni tó ń mú wọn dúró (sínú òfurufú) bí kò ṣe Allāhu. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ṣe ibùsinmi fún yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan tó fúyẹ́ fún yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn,[1] irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ṣe àwọn ibòji fún yín láti ara àwọn n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fún yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fún yín tó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ tó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín.[1] Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú ni ojúṣe tìrẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n mọ ìdẹ̀ra Allāhu, lẹ́yìn náà wọ́n ń takò ó. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni aláìmoore.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn tó ṣàbòsí bá rí Ìyà, nígbà náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí lọ́ wọn lára láti wọ (inú Iná).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn tó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ bá rí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni àwọn òrìṣà wa tí à ń pè lẹ́yìn Rẹ.” Nígbà náà (àwọn òrìṣà) yóò ju ọ̀rọ̀ náà padà sí wọ́n pé: “Dájúdájú òpùrọ́ mà ni ẹ̀yin.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa jura wọn sílẹ̀ fún Allāhu ní ọjọ́ yẹn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn ni nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan,[1] ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ sì mú àdéhùn Allāhu ṣẹ nígbà tí ẹ bá ṣe àdéhùn. Ẹ má ṣe tú ìbúra lẹ́yìn ìfirinlẹ̀ rẹ̀. Ẹ sì kúkú ti fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí lórí ara yín. Dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ sì má ṣe dà bí (obìnrin) èyí tí ó tú òwú dídì rẹ̀ palẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ lẹ́yìn tí ó tí dì í le. Ńṣe ni ẹ̀ ń lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín nítorí pé ìran kan pọ̀ ju ìran kan. Dájúdájú Allāhu ń dan yín wò pẹ̀lú rẹ̀ ni. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde Ó kúkú máa ṣàlàyé fún yín ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n Ó ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Dájúdájú wọ́n máa bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín, nítorí kí ẹsẹ̀ yín má baà yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìdúróṣinṣin rẹ̀, àti nítorí kí ẹ má baà tọ́ ìyà burúkú wò nípa bí ẹ ṣe ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Ìyà ńlá yó sì wà fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe ta àdéhùn Allāhu ní owó pọ́ọ́kú. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu, ó lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa san àwọn tó ṣe sùúrù ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí o bá (fẹ́) ké al-Ƙur’ān, sá di Allāhu níbi (aburú) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú kò sí agbára kan fún un lórí àwọn tó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí (aṣ-Ṣaetọ̄n) lágbára lórí rẹ̀ ni àwọn tó ń mú un ní ọ̀rẹ́ àti àwọn tó sọ ọ́ di akẹgbẹ́ Allāhu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ló sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ pẹ̀lú òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan ló ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń darí al-Ƙur’ān kọ ní ọ̀nà òdì (pé ó ń kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu ló ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn gan-an sì ni òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣí igbá-àyà rẹ̀ sílẹ̀ fún àìgbàgbọ́, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni afọ́núfọ́ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé tí yóò máa rojọ́ gbe ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, tó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tó yàtọ́ sí “Allāhu”. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi.[1] A kò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó ṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe - lẹ́yìn rẹ̀ (lẹ́yìn ìronú-pìwàdà) dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa ń dúpẹ́ àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Allāhu ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣe ohun rere fún un nílé ayé. Àti pé ní ọ̀run dájúdájú ó máa wà nínú àwọn ẹni rere.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀.[1] Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniPèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí tó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Òun l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ (bá fẹ́) gbẹ̀san (ìyà), ẹ gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣe sùúrù, òhun ló mà lóore jùlọ fún àwọn onísùúrù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢe sùúrù. Ìwọ kò sì lè rí sùúrù ṣe àfi pẹ̀lú (ìrànlọ́wọ́) Allāhu. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì ṣe wà nínú ìbànújẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń dá ní ète.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn tó ń ṣe rere.