الإسراء
Al-Isra
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì ṣe é ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (A sì sọ) pé: “Ẹ má ṣe mú aláààbò kan lẹ́yìn Mi.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ jẹ́) àrọ́mọdọ́mọ àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh. Dájúdájú (Nūh) jẹ́ ẹrúsìn, olùdúpẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì.[1] Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga tó tóbi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, nígbà tí àdéhùn fún àkọ́kọ́ nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀,[1] A máa gbé àwọn ẹrúsìn Wa kan, tí wọ́n lágbára gan-an, dìde si yín. Wọn yóò dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láààrin ìlú (yín). Ó jẹ́ àdéhùn kan tí A máa mú ṣẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A dá ìṣẹ́gun lórí wọn padà fún yín. A sì fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ ṣèrànwọ́ fún yín. A sì ṣe yín ní ìjọ tó pọ̀ jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ bá ṣe rere, ẹ ṣe rere fún ẹ̀mí ara yín. Tí ẹ bá sì ṣe aburú, fún ẹ̀mí ara yín ni. Nígbà tí àdéhùn ìkẹ́yìn bá dé, (A óò gbé ọmọ ogun mìíràn dìde) nítorí kí wọ́n lè kó ìbànújẹ́ bá yín àti nítorí kí wọ́n lè wọ inú Mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wọ̀ ọ́ nígbà àkọ́kọ́ àti nítorí kí wọ́n lè pa ohun tí (àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl) jọba lórí rẹ̀ run pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ lè jẹ́ pé Olúwa yín máa ṣààánú yín. Tí ẹ bá sì padà (síbi ẹ̀ṣẹ̀), A máa padà (síbi ẹ̀san). A sì ṣe iná Jahanamọ ní ẹ̀wọ̀n fún àwọn aláìgbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà, ó sì ń fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san tó tóbi wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈnìyàn ń tọrọ aburú bí ó ṣe ń tọrọ ohun rere; ènìyàn sì jẹ́ olùkánjú.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran[1] nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (àwọn ọjọ́). Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.[2]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈnìyàn kọ̀ọ̀kan, A ti so iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKa ìwé (iṣẹ́) rẹ. Ìwọ ti tó ní olùṣírò fún ẹ̀mí ara rẹ lónìí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá sì ṣìnà, ó ń ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.[1] A ò sì níí jẹ àwọn ẹ̀dá níyà títí A fi máa gbé òjíṣẹ́ kan dìde (sí wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun lẹ́yìn (Ànábì) Nūh! Olúwa rẹ tó ní Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹrúsìn Rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni èébú, ẹni ẹ̀kọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀run náà, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, wọ́n máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ wọn fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ayé) àti àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ọ̀run), gbogbo wọn ni À ń ṣe oore ayé fún láti inú ọrẹ Olúwa rẹ. Wọn kò níí dí ọrẹ Olúwa rẹ lọ́wọ́ (fún ìkíní kejì nílé ayé).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu nítorí kí o má baà jókòó (sínú Iná) ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀ (tí wọ́n máa dá ìṣòro rẹ̀ dá).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRẹ apá rẹ nílẹ̀ dáadáa (bọ̀wọ̀) fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: “Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì nítorí pé, àwọn méjèèjì náà tọ́ mi ní kékeré.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, tí ẹ bá jẹ́ ẹni rere. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn fún àwọn olùronúpìwàdà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFún ẹbí ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Kí o sì má ṣe ná dúkìá yín ní ìná-àpà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn àpà, wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá àwọn ṣaetọ̄n. Aláìmoore sì ni aṣ-Ṣaetọ̄n jẹ́ sí Olúwa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn (ìyẹn àwọn aláìní) láti wá ìkẹ́ kan tí ò ń retí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, bá wọn sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá di ọwọ́ rẹ mọ́ ọrùn rẹ (má ya ahun), má sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ tán pátápátá (má ya àpà), kí o má baà jókòó kalẹ̀ ní ẹni èébú (tí o bá jẹ́ ahun), ẹni tí kò níí sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́ (tí o bá jẹ́ àpà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má pa àwọn ọmọ yín nítorí ìpáyà òṣì. Àwa l’À ń pèsè fún àwọn àti ẹ̀yin. Dájúdájú pípa wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe súnmọ́ àgbèrè. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà burúkú. Ó sì burú ní ojú ọ̀nà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.[1] Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san).[2]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn, àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ, títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Kí ẹ sì mú àdéhùn ṣẹ. Dájúdájú àdéhùn jẹ́ ohun tí A ó bèèrè nípa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ wọn òṣùwọ̀n kún nígbà tí ẹ bá wọ̀n ọ́n. Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọ̀n ọ́n. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ ní ìkángun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe tẹ̀lé ohun tí ìwọ kò nímọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga; dájúdájú ìwọ kò lè dá ilẹ̀ lu, ìwọ kò sì lè ga tó àpáta.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo ìyẹn, aburú rẹ̀ jẹ́ ohun ìkórira lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn wà nínú ohun tí Olúwa rẹ fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n (al-Ƙur’ān). Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu kí wọ́n má baà jù ọ́ sínú iná Jahanamọ ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé Olúwa yín fi àwọn ọmọkùnrin ṣà yín lẹ́ṣà, Òun wá mú àwọn ọmọbìnrin nínú àwọn mọlāika (ní tiRẹ̀)? Dájúdájú ẹ mà ń sọ ọ̀rọ̀ ńlá (tó burú).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMímọ́ ni fún Un. Ó sì ga ní gíga tó tóbi tayọ ohun tí wọ́n ń wí (ní àìda nípa Rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn sánmọ̀ méjèèje, ilẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wà nínú wọn ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. Kò sì sí kiní kan àfi kí ó máa ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.[1] Ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbọ́ àgbọ́yé àfọ̀mọ́ wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí o bá ń ké al-Ƙur’ān, A máa fi gàgá ààbò sáààrin ìwọ àti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur’ān, wọ́n máa pẹ̀yìndà tí wọn yóò máa sá lọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń gbọ́ nígbà tí wọ́n bá ń tẹ́tí sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, nígbà tí àwọn alábòsí bá ń wí pé: “Ẹ kò tẹ̀lé ẹnì kan bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a ti jẹrà, ṣé Wọ́n máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ di òkúta tàbí irin.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí (kí ẹ di) ẹ̀dá kan nínú ohun tí ó tóbi nínú ọkàn yín.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò wí pé: “Ta ni Ó máa dá wa padà (fún àjíǹde)?” Sọ pé: “Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá yín ní ìgbà àkọ́kọ́ ni.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò mi orí wọn sí ọ (ní ti àbùkù). Nígbà náà, wọn yóò wí pé: “Ìgbà wo ni?” Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ó ti súnmọ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí Allāhu yóò pè yín. Ẹ sì máa jẹ́pè pẹ̀lú ẹyìn Rẹ̀. Ẹ sì máa lérò pé ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n máa sọ èyí tó dára jùlọ (nínú ọ̀rọ̀). Dájúdájú aṣ-Ṣaetọ̄n yóò máa dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Dájúdájú aṣ-Ṣaetọ̄n jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa yín. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa kẹ yín. Tàbí tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa jẹ yín níyà. A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ lórí wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú A ti ṣe oore àjùlọ fún apá kan àwọn Ànábì lórí apá kan. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ nípa wọn - láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ - pé wọ́n jẹ́ ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀, (ẹ máa rí i pé) wọn kò ní ìkápá láti gbé ìnira kúrò tàbí láti ṣe ìyípadà kan fún yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn ló súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? - Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìlú kan (tó ṣàbòsí) àfi kí Àwa pa á rẹ́ ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde tàbí kí Á jẹ ẹ́ níyà líle. Ìyẹn ti wà ní kíkọ sílẹ̀ nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) tó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré tó tóbi.[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs. Ó wí pé: “Ṣé kí n̄g forí kanlẹ̀ kí ẹni tí O fi ẹrẹ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ wí pé: “Sọ fún mi nípa èyí tí O gbé àpọ́nlé fún lórí mí, (nítorí kí ni?) Dájúdájú tí O bá lè lọ́ mi lára di Ọjọ́ Àjíǹde, dájúdájú mo máa jẹgàba lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Máa lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú iná Jahanamọ ni ẹ̀san yín. (Ó sì jẹ́) ẹ̀san tó kún kẹ́kẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ.[1] Kí o sì ṣe àdéhùn fún wọn.” Aṣ-ṣaetọ̄n kò sì níí ṣe àdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn. [2]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn. Olúwa rẹ sì tó ní Olùṣọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa yín ni Ẹni tó ń mú ọkọ̀ ojú-omi rìn fún yín nítorí kí ẹ lè wá nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláàánú fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ìnira bá fọwọ́ bà yín lójú omi, ẹni tí ẹ̀ ń pè yó sì dòfo (mọ yín lọ́wọ́) àfi Òun nìkan (Allāhu). Nígbà ti Ó bá sì gbà yín là (tí ẹ) gúnlẹ̀ sórí ilẹ̀, ẹ̀ ń gbúnrí (kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀). Ènìyàn sì jẹ́ aláìmoore.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò lè mú apá kan ilẹ̀ ri mọ yín lẹ́sẹ̀ ni? Tàbí pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín? Lẹ́yìn náà, ẹ̀ ko níí rí olùṣọ́ kan tí ó máa gbà yín là.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò níí padà mu yín wá sí (orí omi) nígbà mìíràn ni; tí Ó máa rán ìjì atẹ́gùn si yín, tí Ó sì máa tẹ̀ yín rì (sínú omi) nítorí pé ẹ ṣàì moore? Lẹ́yìn náà, ẹ ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tó máa ba yín gbẹ̀san lára Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn[1]. Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí fi ìbójú kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ afọ́jú (nípa ’Islām) nílé ayé yìí, òun ni afọ́jú ní ọ̀run. Ó sì (ti) ṣìnà jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí kò bá jẹ́ pé A fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ ni, dájúdájú o fẹ́ẹ̀ fi n̄ǹkan díẹ̀ tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, Àwa ìbá jẹ́ kí o tọ́ ìlọ́po (ìyà) ìṣẹ̀mí ayé àti ìlọ́po (ìyà lẹ́yìn) ikú wò. Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tí ó máa gbà ọ́ sílẹ̀ níbi ìyà Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n fẹ́ẹ̀ pin ọ́ lẹ́mìí nínú ìlú nítorí kí wọ́n lè lé ọ jáde kúrò nínú rẹ̀. Nígbà náà, àwọn náà kò níí wà nínú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ tayọ ìgbà díẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èyí jẹ́) ìṣe (Allāhu) lórí àwọn tí A ti rán níṣẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ṣíwájú rẹ. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbé ìrun kíkí dúró ní (ìgbà tí) òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí alẹ́ yóò fi lẹ́. Àti pé ìrun Subh, dájúdájú ìrun Subh jẹ́ ohun tí (àwọn mọlāika alẹ́ àti ọ̀sán) yóò jẹ́rìí sí.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé nínú òru, fi kíké al-Ƙur’ān (lórí ìrun) ṣàì sùn. (Èyí jẹ́) iṣẹ́ àṣegbọrẹ fún ọ. Láìpẹ́, Olúwa rẹ yóò gbé ọ sí ipò kan tí àwọn ẹ̀dá máa ti yìn ọ́.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Olúwa mi, mú mi wọ inú ìlú ní ìwọ̀lú ọ̀nà òdodo. Mú mi jáde kúrò nínú ìlú ní ìjáde ọ̀nà òdodo. Kí O sì fún mi ní àrànṣe tó lágbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Òdodo dé. Irọ́ sì sá lọ. Dájúdájú irọ́ jẹ́ ohun tí ó máa sá lọ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀ ń sọ ohun tí ó jẹ́ ìwòsàn àti ìkẹ́ kalẹ̀ sínú al-Ƙur’ān fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (al-Ƙur’ān) kò sì ṣàlékún fún àwọn alábòsí bí kò ṣe òfò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí A bá ṣèdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò níbi òdodo), ó sì máa takété (sí àṣẹ Allāhu). Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣiṣẹ́ lórí àdámọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mọ̀nà.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ẹ̀mí. Sọ pé: “Ẹ̀mí ń bẹ nínú àṣẹ Olúwa mi. A ò sì fún yín nínú ìmọ̀ bí kò ṣe díẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú tí A bá fẹ́ ni, A ìbá kúkú gba ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ). Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí aláàbò kan tí ó máa là ọ́ lọ́dọ̀ Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ (ni kò fi ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú oore àjùlọ Rẹ̀ lórí rẹ tóbi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Dájúdájú tí àwọn ènìyàn àti àlùjànnú bá parapọ̀ láti mú irú al-Ƙur’ān yìí wá, wọn kò lè mú irú rẹ̀ wá, apá kan wọn ìbáà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún apá kan.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti fi àkàwé kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé (oríṣiríṣi) fún àwọn ènìyàn sínú al-Ƙur’ān yìí. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì wí pé: “A kò níí gbàgbọ́ nínú rẹ títí o máa fi mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́yọ fún wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí kí o ní ọgbà oko dàbínù àti ọgbà oko àjàrà, tí o sì máa jẹ́ kí àwọn odò ṣàn kọ já dáadáa láààrin wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí kí o jẹ́ kí sánmọ̀ já lù wá ní kélekèle gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ (pé Allāhu lè ṣe bẹ́ẹ̀). Tàbí kí o mú Allāhu àti àwọn mọlāika wá (bá wa) ní ojúkojú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí kí o ní ilé wúrà kan, tàbí kí o gun òkè sánmọ̀ lọ. A kò sì níí gba gígun-sánmọ̀ rẹ gbọ́ títí o fi máa sọ tírà kan tí a óò máa ké kalẹ̀ fún wa.” Sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa mi, ǹjẹ́ mo jẹ́ kiní kan bí kò ṣe Òjíṣẹ́ abara?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ohun tí ó kọ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Ṣé Allāhu rán Òjíṣẹ́ abara níṣẹ́ ni?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o kò níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Àti pé A máa kó wọn jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìdojúbolẹ̀. (Wọn yóò di) afọ́jú, ayaya àti odi. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Nígbàkígbà tí Iná bá jó lọọlẹ̀, A óò máa ṣàlékún iná (mìíràn) tó ń jó fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a sì ti jẹrà, ṣé wọ́n tún máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ lágbára láti ṣẹ̀dá irú wọn (mìíràn)? Ó sì máa fún wọn ní gbèdéke àkókò kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn alábòsí kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin l’ẹ ni ìkápá lórí àwọn ilé ọrọ̀ ìkẹ́ Olúwa mi ni, nígbà náà ẹ̀yin ìbá diwọ́ mọ́ ọn ní ti ìbẹ̀rù òṣì. Ènìyàn sì jẹ́ ahun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní àwọn àmì mẹ́sàn-án tó yanjú. Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè wò. Rántí, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ wọn, Fir‘aon wí fún un pé: “Dájúdájú èmi lérò pé eléèdì ni ọ́, Mūsā.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Mūsā) sọ pé: “O kúkú mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó sọ àwọn (àmì) wọ̀nyí kalẹ̀ bí kò ṣe Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (ó sì jẹ́) ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Dájúdájú èmi náà lérò pé ẹni ìparun ni ọ́, Fir‘aon.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, (Fir‘aon) fẹ́ kó ìdààmú bá wọn lórí ilẹ̀. A sì tẹ òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ rì pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì sọ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ pé: “Ẹ máa gbé orí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Àdéhùn Ìkẹ́yìn bá dé, A óò mú gbogbo yín wá ní àpapọ̀ (ní ọjọ́ ẹ̀san).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé al-Ƙur’ān, A ṣàlàyé rẹ̀ (fún ọ) nítorí kí o lè ké e fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān tàbí ẹ kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa. Dájúdájú àdéhùn Olúwa wa máa wá sí ìmúṣẹ ni.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò máa sunkún (fún Allāhu. Al-Ƙur’ān) sì ń ṣàlékún ìtẹríba fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).”[1] Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,[1] Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò sì ní ọ̀rẹ́ kan torí àìlágbára.”[2] Gbé títóbi fún Un gan-an.