الحج

Al-Hajj

Sūrah 22 · ti Mẹdīnah · āyah 78 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 103

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Dájúdájú ìmì tìtì Àkókò náà, n̄ǹkan ńlá ni.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àkókò náà ni) ọjọ́ tí ẹ máa rí i tí gbogbo obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú mu yóò gbàgbé ọmọ tí ó ń fún lọ́mú àti pé gbogbo aboyún yó sì máa bí oyún wọn. Ìwọ yó sì rí àwọn ènìyàn tí ọtí yóò máa pa wọ́n. Ọtí kò sì pa wọ́n, ṣùgbọ́n ìyà Allāhu (tó) le (ló fà á).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀. Ó sì ń tẹ̀lé gbogbo aṣ-Ṣaetọ̄n olórí kunkun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kọ ọ́ lé (aṣ-ṣaetọ̄n) lórí pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé e, ó máa ṣì í lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ọ sí ọ̀nà ìyà Iná tó ń jo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fún yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí wọ́n máa pa (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí wọ́n máa dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn tó dára jáde.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn tó ń bẹ nínú sàréè dìde.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (sunnah Ànábì) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń ṣègbéraga (sí òdodo, ó ń gbúnrí kúrò níbi òdodo) nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá àwọn ènìyàn lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àbùkù ń bẹ fún un nílé ayé. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, A sì máa fún un ní ìyà Iná jónijóni tọ́ wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ tì síwájú. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jọ́sìn fún Allāhu lórí ahọ́n. Tí rere bá ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa fi ọkàn balẹ̀ (sínú ẹ̀sìn). Tí ìfòòró bá sì ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa yíjú rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Ó ṣòfò láyé àti lọ́run. Ìyẹn sì ni òfò pọ́nńbélé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń pè lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè kó ìnira bá a, tí kò sì lè ṣe é ní oore; ìyẹn ni ìṣìnà tó jìnnà (sí ìmọ̀nà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń pe ohun tí ìnira rẹ̀ súnmọ́ ju àǹfààní rẹ̀ lọ. Dájúdájú (òrìṣà) burú ní aláfẹ̀yìntì, ó sì burú ní alásùn-únmọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu yóò mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá lérò pé Allāhu kò níí ran (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lọ́wọ́ láyé àti lọ́run, kí ó na okùn sí sánmọ̀ (àjà ilé rẹ̀) lẹ́yìn náà kí ó gé e (ìyẹn ni pé, kí ó pokùn so). Kí ó wò ó nígbà náà bóyá ète rẹ̀ lè mú (àrànṣe) tó ń bínú sí kúrò (lọ́dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní àwọn āyah tó yanjú. Dájúdájú Allāhu ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi àti àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn mọjūs àti àwọn tó ṣẹbọ, dájúdájú Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò wòye pé dájúdájú Allāhu ni àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn oníjà méjì (kan) nìyí, wọ́n ń takò ara wọn nípa Olúwa wọn. Nítorí náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa gé aṣọ Iná fún wọn, wọ́n yó sì máa da omi tó gbóná gan-an lé wọn lórí láti òkè orí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa fi yọ́ ohun tí ń bẹ nínú ikùn wọn àti awọ ara wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn òdùrọ irin (ìyà) sì wà fún wọn pẹ̀lú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀ látara ìbànújẹ́, wọ́n á dá wọn padà sínú rẹ̀. (A óò sọ pé): “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. A óò ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà àti àlúùlúù. Aṣọ àlàárì sì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA fún wọn ní ìmọ̀nà síbi ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀.[1] A sì tọ́ wọn sí ọ̀nà Ẹlẹ́yìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti Mọ́sálásí Haram, èyí tí A ṣe ní dọ́gbadọ́gba fún àwọn ènìyàn, olùgbé-inú rẹ̀ àti àlejò (fún ìjọ́sìn ṣíṣe), ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀ àti lórí gbogbo n̄ǹkan ìgùn, wọn yóò máa wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní tó ń bẹ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ṣèrántí orúkọ Allāhu fún àwọn ọjọ́ tí wọ́n ti mọ̀[1] lórí n̄ǹkan tí Allāhu pa lésè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu bu ọ̀wọ̀ fún, òhun ló lóore jùlọ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fún yín àyàfi àwọn tí wọ́n ń kà (ní èèwọ̀) fún yín. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí ẹ̀gbin òrìṣà. Kí ẹ sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa ṣẹbọ sí I. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹbọ sí Allāhu, ó dà bí ẹni tó jábọ́ láti ojú sánmọ̀, tí ẹyẹ sì gbé e lọ tàbí (tí) atẹ́gùn jù ú sínú àyè tó jìnnà.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn ’Islām, dájúdájú ó wà lára níní ìbẹ̀rù Allāhu nínú ọkàn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn àǹfààní wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, Ilé Láéláé náà ni ibùpa àwọn ẹran náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌkọ̀ọ̀kan ìjọ (mùsùlùmí tó ṣíwájú) ni A yan ẹran pípa fún nítorí kí wọ́n lè dárúkọ Allāhu lórí ohun tí Ó pèsè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Òun ni kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí fún. Kí o sì fún àwọn ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀, àwọn olùfọkànbalẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ní ìró ìdùnnú.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá dárúkọ Allāhu (fún wọn), ọkàn wọn máa gbọ̀n rìrì. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Wọ́n jẹ́) olùkírun. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pa lésè fùn wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fún yín. Oore wà lára wọn fún yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸran (tí ẹ pa) àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò níí dé ọ̀dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Allāhu láti ọ̀dọ̀ yín ló máa dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Báyẹn ni (Allāhu) ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe ìgbétóbi fún Allāhu nípa bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín. Kí o sì fún àwọn olùṣe-rere ní ìró ìdùnnú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ń ti aburú kúrò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn oníjàǹbá, aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.[1] Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ìjọ ’Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (tó ti dahoro)!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn tó wà nínú igbá-àyà ló ń fọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMélòó mélòó nínú ìlú tí Mo lọ́ lára, tí wọ́n jẹ́ alábòsí. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, èmi mà ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, aṣ-Ṣaetọ̄n máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí aṣ-Ṣaetọ̄n ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. [1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè fi ohun tí aṣ-Ṣaetọ̄n ń jù (sínú rẹ̀) ṣe àdánwò fún àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn tí ọkàn wọn le. Dájúdájú àwọn alábòsí sì wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní ìmọ̀ lè mọ̀ pé dájúdájú al-Ƙur’ān jẹ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, wọn yó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ọkàn wọn yó sì balẹ̀ sí i. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò sì níí yé wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ títí Àkókò náà yóò fi dé bá wọn ní òjijì tàbí (títí) ìyà ọjọ́ ìparun yóò fi dé bá wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, lẹ́yìn náà, tí wọ́n pa wọ́n tàbí tí wọ́n kú; dájúdájú Allāhu yóò pèsè fún wọn ní ìpèsè tó dára. Dájúdájú Allāhu, Ó mà l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Allāhu) yóò fi wọ́n sínú àyè kan tí wọn yóò yọ́nú sí. Dájúdájú Allāhu mà ni Onímọ̀, Aláfaradà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, lẹ́yìn náà tí wọ́n bá tún ṣàbòsí sí i, dájúdájú Allāhu yóò ṣàrànṣe fún un. Dájúdájú Allāhu mà ni Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ń fi òru bọ inú ọ̀sán, Ó sì ń fi ọ̀sán bọ inú òru. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, ilẹ̀ sì máa lọ́ràá wá? Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun mà ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, àti ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ sórí ilẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun sì ni Ẹni tó ṣe yín ni alààyè, lẹ́yìn náà Ó ń sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà Ó máa sọ yín di alààyè. Dájúdájú ènìyàn mà ni aláìmoore.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà. [1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ nígbà náà pé: “Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu máa ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ń jọ́sìn fún ohun míiràn lẹ́yìn Allāhu tí (Allāhu) kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún àti ohun tí kò sí ìmọ̀ kan fún wọn lórí rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, o máa rí ohun tí ẹ̀mí kọ̀ (ìkorò-ojú) nínú ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́; wọn sì fẹ́ẹ̀ fọwọ́ ìnira kan àwọn tí ń ké àwọn āyah Wa fún wọn. Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró ohun tó burú ju ìyẹn? Iná tí Allāhu ṣèlérí rẹ̀ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni. Ìkángun náà sì burú.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin náà bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, kí ẹ sì ṣe rere nítorí kí ẹ lè jèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn.[1] Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.