المؤمنون

Al-Mu'minun

Sūrah 23 · ti Mọkkah · āyah 118 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 74

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí àti ara) wọn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà,[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń ṣọ́ ìrun wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú ẹrẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ìrọ̀rùn kan (ìyẹn, ilé-ọmọ).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.[1] Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yóò di òkú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde wọ́n máa gbe yín dìde.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀ ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A fi dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fún yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fún yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti igi kan tó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā’; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn tó ń jẹ ẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fún yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àǹfààní (mìíràn) tún wà fún yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn olórí tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn tó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ó ń ṣe àdéhùn fún yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Àti pé wọn kò níí gbé wa dìde mọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ohùn igbe mú wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) sẹ́yìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n á pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ ní òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn olùparun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, tó ní ibùgbé, tó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunini A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni![1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) nípa ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tí wọ́n ń ṣe ohun wọ́n ń ṣe (nínú àwọn iṣẹ́ rere) pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan tó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur’ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn.[1] Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa kígbe (fún ìrànlọ́wọ́).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) ní òní. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fún yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀ sì ń fi (Kaaba) ṣègbéraga, ẹ tún sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur’ān) ní alẹ́!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun tó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn tó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí kò sì gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-ààlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú ti ṣàdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá tó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn mí,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn ọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFi èyí tó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t’àwọn aṣ-ṣaetọ̄n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: “Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí kí èmi lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fún yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é ní irọ́?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Olúwa wa, orí burúkú ló kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn gan-an ni olùjèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”[1]