النور
An-Nur
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe ìdájọ́ inú rẹ̀ ní òfin (dandan). A sì sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOnísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOnísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin.[1] A sì ṣe ìyẹn (sìná ṣíṣe) ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.[2]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ìyàwó wọn, tí kò sì sí ẹlẹ́rìí fún wọn àfi àwọn fúnra wọn, ẹ̀rí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú òun wà nínú àwọn olódodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ibi dandan Allāhu máa bá òun, tí òun bá wà nínú àwọn òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí ó máa yẹ ìyà fún ìyàwó ni pé, kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú ọkọ òun wà nínú àwọn òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ìbínú Allāhu máa bá òun, tí ọkọ òun bá wà nínú àwọn olódodo.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá máa tú àṣírí yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó mú àdápa irọ́ wá jẹ́ ìjọ kan nínú yín. Ẹ má ṣe lérò pé aburú ni fún yín. Rárá o, oore ni fún yín. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ti ní ohun tí ó dá ní ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé ẹni tí ó dá (ẹ̀ṣẹ̀) jùlọ nínú wọn, ìyà ńlá ni tirẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin ro dáadáa rora wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni àdápa irọ́ pọ́nńbélé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá lórí rẹ̀? Nítorí náà, nígbà tí wọn kò ti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òpùrọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ní ilé ayé àti ní ọ̀run ni, dájúdájú ìyà ńlá ìbá fọwọ́ bà yín nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ kiri ní ìsọkúsọ.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gbà á (láààrin ara yín) pẹ̀lú ahọ́n yín, tí ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀; ẹ lérò pé n̄ǹkan tó fúyẹ́ ni, n̄ǹkan ńlá sì ni lọ́dọ̀ Allāhu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí ẹ sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún wa pé kí á sọ èyí. Mímọ́ ni fún Ọ (Allāhu)! Èyí ni ìparọ́-mọ́ni tó tóbi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ń ṣe wáàsí fún yín pé kí ẹ má ṣe padà síbi irú rẹ̀ mọ́ láéláé tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí kí (ọ̀rọ̀) ìbàjẹ́ máa tàn kálẹ̀ nípa àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá tètè fìyà jẹ yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-ṣaetọ̄n. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-ṣaetọ̄n, dájúdájú (aṣ-ṣaetọ̄n) yóò pàṣẹ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú (fún un). Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni, ẹnì kan kan ìbá tí mọ́ nínú yín láéláé. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àwọn tó ní ọlá àti ọrọ̀ púpọ̀ nínú yín má ṣe búra pé àwọn kò níí ṣe dáadáa sí àwọn ìbátan, àwọn mẹ̀kúnnù àti àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Kí wọ́n ṣàforíjìn, kí wọ́n sì ṣàmójúkúrò. Ṣé ẹ kò fẹ́ kí Allāhu foríjìn yín ni? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń parọ́ sìná mọ́ àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, A ti ṣẹ́bilé wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí àwọn ahọ́n wọn, ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn yóò máa jẹ́rìí takò wọ́n nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọjọ́ yẹn ni Allāhu yóò san wọ́n ní ẹ̀san wọn tí ó tọ́ sí wọn. Wọn yó sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo pọ́nńbélé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn obìnrin burúkú wà fún àwọn ọkùnrin burúkú. Àwọn ọkùnrin burúkú sì wà fún àwọn obìnrin burúkú. Àwọn obìnrin rere wà fún àwọn ọkùnrin rere. Àwọn ọkùnrin rere sì wà fún àwọn obìnrin rere.[1] Àwọn (ẹni rere) wọ̀nyí mọ́wọ́-mọ́sẹ̀ nínú (àìdaa) tí wọ́n ń sọ sí wọn. Àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn ilé kan yàtọ̀ sí àwọn ilé yín títí ẹ máa fi tọrọ ìyọ̀ǹda àti (títí) ẹ máa fi sálámọ̀ sí àwọn ará inú ilé náà. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ ò bá sì bá ẹnì kan kan nínú ilé náà, ẹ má ṣe wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi yọ̀ǹda fún yín. Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé kí ẹ padà, nítorí náà ẹ padà. Òhun ló fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti wọ inú àwọn ilé kan tí kì í ṣe ibùgbé, tí àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún yín[1]. Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Ìyẹn fọ̀ wọ́n mọ́ jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀[1]. Kí wọ́n fi ìbòrí wọn bo igbá-àyà wọn. Àti pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn tàbí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn bàbá ọkọ wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin ọkọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn tàbí àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn tàbí àwọn ẹrúkùnrin wọn tàbí àwọn tó ń tẹ̀lé obìnrin fún iṣẹ́ rírán, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin akúra tàbí àwọn ọmọdé tí kò dá ìhòhò àwọn obìnrin mọ̀. Wọn kò gbọ́dọ̀ fi ẹsẹ̀ wọn rin ìrin-kokokà nítorí kí àwọn (ènìyàn) lè mọ ohun tí wọ́n fi pamọ́ (sára) nínú ọ̀ṣọ́ wọn. Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ so yìgì fún àwọn ọkùnrin tí kò ní aya àti àwọn obìnrin tí kò ní ọkọ láààrin yín, (ẹ tún so yìgì) fún àwọn ẹni rere nínú àwọn ẹrúkùnrin yín àti àwọn ẹrúbìnrin yín. Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Allāhu sì ni Olùgbààye, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.[1] Àwọn tó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fún yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.[2] Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá.[3]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti sọ àwọn àmì tó yanjú, ìtàn àwọn tó ti lọ ṣíwájú yín àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) kalẹ̀ fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan tó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn, tí kò gba ìmọ́lẹ̀ ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn (nìkan mọ).[1] Epo rẹ̀ fẹ́rẹ̀ tànmọ́lẹ̀, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni.[2] Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn àtùpà ìbùkún náà wà) nínú àwọn ilé kan (ìyẹn àwọn mọ́sálásí) èyí tí Allāhu yọ̀ǹda pé kí wọ́n gbéga,[1] kí wọ́n sì máa dárúkọ Rẹ̀ nínú rẹ̀. (Àwọn ènìyàn) yó sì máa ṣàfọ̀mọ́ fún Un nínú rẹ̀ ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́;[2]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ọkùnrin tí òwò àti kárà-kátà kò dí lọ́wọ́ níbi ìrántí Allāhu, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ, tí wọ́n ń páyà ọjọ́ kan tí àwọn ọkàn àti ojú yóò máa yí sí ọ̀tún yí sí òsì.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n ṣe rere wọ̀nyí) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere tó dára ju ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ wọn dà bí ahúnpeéná tó wà ní pápá, tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ sì lérò pé omi ni títí di ìgbà tí ó dé síbẹ̀, kò sì bá n̄ǹkan kan níbẹ̀. Ó sì bá Allāhu níbi (iṣẹ́) rẹ̀ (ní ọ̀run). (Allāhu) sì ṣe àṣepé ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí (iṣẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí àwọn òkùnkùn kan nínú ibúdò jíjìn, tí ìgbì omi ń bò ó mọ́lẹ̀, tí ìgbì omi mìíràn tún wà ní òkè rẹ̀, tí ẹ̀ṣújò sì wà ní òkè rẹ̀; àwọn òkùnkùn biribiri tí apá kan wọ́n wà lórí apá kan (nìyí). Nígbà tí ó bá nawọ́ ara rẹ̀ jáde, kò ní fẹ́ẹ̀ rí i. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu kò bá fún ní ìmọ́lẹ̀, kò lè sí ìmọ́lẹ̀ kan fún un.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ni gbogbo ẹni tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún? Àwọn ẹyẹ náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n bá ń na ìyẹ́ apá wọn? Ìkọ̀ọ̀kan wọn kúkú ti mọ bí ó ṣe máa kírun rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ (fún Un). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Allāhu ń da ẹ̀ṣújò káàkiri ni? Lẹ́yìn náà Ó ń kó o jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbé wọn gun ara wọn, nígbà náà ni o máa rí òjò tí ó máa jáde láti ààrin rẹ̀. Láti inú sánmọ̀, Ó sì ń sọ àwọn yìyín kan (tó dà bí) àwọn àpáta kalẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé. Ó ń mú un kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Kíkọ yànrànyànràn mọ̀nàmọ́ná inú ẹ̀ṣújò sì fẹ́ẹ̀ lè fọ́ àwọn ojú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ń yí òru àti ọ̀sán padà (ìkíní kejì n wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé pẹ̀lú àlékún àti àdínkù). Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn tó ní ojú ìríran.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ṣẹ̀dá gbogbo abẹ̀mí láti inú omi. Ó wà nínú wọn, èyí tó ń fi àyà rẹ̀ wọ́. Ó wà nínú wọn, èyí tó ń fi ẹsẹ̀ méjì rìn. Ó sì wà nínú wọn, èyí tó ń fi mẹ́rin rìn. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó ń yanjú ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Allāhu sì ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ náà. A sì tẹ̀lé (àṣẹ wọn).” Lẹ́yìn náà, igun kan nínú wọn ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa gbúnrí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ni wọ́n ni ẹ̀tọ́ (àre) ni, wọn yóò wá bá ọ ní tọkàn-tara.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àrùn wà nínú ọkàn wọn ni tàbí wọ́n ṣeyèméjì? Tàbí wọ́n ń páyà pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yóò fi ẹjọ́ wọn ṣègbè ni? Rárá o. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí ó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn ni pé, wọ́n á sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ).” Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó ń páyà Allāhu, tí ó sì ń bẹ̀rù Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbura wọn sì ní agbára pé: “Dájúdájú tí o bá pàṣẹ fún àwọn, dájúdájú àwọn yóò jáde.” Sọ pé: “Ẹ má ṣe búra mọ́. Títẹ̀lé àṣẹ (pẹ̀lú ìbúra irọ́ ẹnu yín) ti di ohun mímọ̀ (fún wa).” Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́ náà. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, ohun tí A gbé kà á lọ́rùn ló ń bẹ lọ́rùn rẹ̀, ohun tí A sì gbé kà yín lọ́rùn ló ń bẹ lọ́rùn yín. Tí ẹ bá sì tẹ̀lé e, ẹ ti mọ̀nà tààrà. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ṣàdéhùn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe àrólé.[1] Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà nítorí kí A lè kẹ yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe lérò pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀. Iná ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí àwọn ẹrú yín àti àwọn tí kò tí ì bàlágà nínú yín máa gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ yín nígbà mẹ́ta (wọ̀nyí): ṣíwájú ìrun Subh, nígbà tí ẹ bá ń bọ́ aṣọ yín sílẹ̀ fún òòrùn ọ̀sán àti lẹ́yìn ìrun alẹ́. (Ìgbà) mẹ́ta fún ìbọ́rasílẹ̀ yín (nìyí). Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn lẹ́yìn (àsìkò) náà pé kí wọ́n wọlé tọ̀ yín; kí apá kan yín wọlé tọ apá kan. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn ọmọdé yín bá sì bàlágà[1], kí àwọn náà máa gba ìyọ̀ǹda gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe gba ìyọ̀ǹda. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí nínú àwọn obìnrin, àwọn tí kò retí àti lọ́kọ mọ́ (tí kò retí ìbálòpò oorun ìfẹ́ mọ́), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn láti bọ́ àwọn aṣọ jilbāb wọn sílẹ̀, tí wọn kò sì níí ṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ kan síta. Kí wọ́n kóra wọn ní ìjánu (kí wọ́n máa wọ aṣọ jilbāb wọn lọ bẹ́ẹ̀) lóore jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà láti jẹun nínú ilé yín, tàbí ilé àwọn bàbá yín, tàbí ilé àwọn ìyá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin ìyá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin ìyá yín, tàbí (ilé) tí ẹ ní ìkápá lórí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, tàbí (ilé) ọ̀rẹ́ yín. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti jẹun papọ̀ tàbí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, tí ẹ bá wọ àwọn inú ilé kan, ẹ sálámọ̀ síra yín. (Èyí jẹ́) ìkíni ìbùkún tó dára láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn onígbàgbọ́ ni àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan tí ó kan gbogbogbò, wọn kò níí lọ títí wọn yóò fi gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú àwọn tó ń gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ fún apá kan ọ̀rọ̀ ara wọn, fún ẹni tí o bá fẹ́ ní ìyọ̀ǹda nínú wọn, kí o sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe ládìsọ́kàn pé ìpè Òjíṣẹ́[1] láààrin yín dà bí ìpè apá kan fún apá kan. Allāhu kúkú ti mọ àwọn tó ń yọ́ sá lọ nínú yín. Nítorí náà, kí àwọn tó ń yapa àṣẹ rẹ̀ ṣọ́ra nítorí kí ìdààmú má baà dé bá wọn, tàbí nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baá jẹ wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbọ́! Dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì ti mọ ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí wọn yó dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.