الشعراء
Ash-Shu'ara
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: “Lọ bá ìjọ alábòsí,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé, ‘Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.’ ”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniO sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláṣìṣe (èmi kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMo sì sá fún yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Lẹ́yìn náà, Allāhu ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí fún àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (tó ń sọ ni)?”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan tó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fẹ́ fi idán rẹ̀ kó yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ[1] sí àwọn ìlú
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: “Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fún yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé), dájúdájú wọn yóò lépa yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni“Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun tó ń bí wa nínú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ilé ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà án). Ó sì pín (sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).[1] Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKa ìtàn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère òrìṣà kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní àǹfààní tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “ Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹ̀yin àti àwọn bàbá yín àwọn ẹni ìṣáájú?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tó ń fún mi ní jíjẹ, tó ń fún mi ní mímu;
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFi òdodo sórí ahọ́n àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi nìpa mi (ìyẹn ni pé, jẹ́ kí àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi máa sọ̀rọ̀ mi ní dáadáa).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniwọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa taari gbogbo wọn ṣubú sínú Iná; àwọn (olùṣìnà) àti àwọn ọ̀gá wọn (nínú ìṣìnà),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni“A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (aṣ-ṣaetọ̄n) ẹlẹ́ṣẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa mọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.)
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA la òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A tẹ àwọn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn wọn rì sínú omi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fún yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o ṣe wáàsí fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn oníwáàsí.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni- Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.[1] –
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí àwọn èso wọn ti gbó?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ olùgbéraga!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn alákọyọ (aláṣejù),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀ (ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fún yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkórira sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn tó ń dín òṣùwọ̀n kù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọn n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a kò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀
- Abu Rahimah Mikael Aykyunisínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀
- Abu Rahimah Mikael Aykyunipẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà ni wọn yóò wí pé: “Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní ìlérí fún wọn dé bá wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKì í ṣe àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ tó súnmọ́ jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá fún yín?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn aṣ-ṣaetọ̄n) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn tó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.