النمل
An-Naml
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTọ̄ sīn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah al-Ƙur’ān àti (àwọn āyah) Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìyà burúkú wà fún. Àwọn sì ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ò ń gba al-Ƙur’ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo rí iná kan. Mo sì máa lọ mú ìró kan wá fún yín láti ibẹ̀, tàbí kí n̄g mú ògúnná kan tó ń tanná wá fún yín nítorí kí ẹ lè yẹ́ná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ó dé ibẹ̀, A pèpè pé kí ìbùkún máa bẹ fún ẹni tí ó wà níbi iná náà àti ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Mímọ́ sì ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMūsā, dájúdájú (ẹni tí ó ń bá ọ sọ̀rọ̀), Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniJu ọ̀pá rẹ sílẹ̀. (Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ nígbà tí ó rí i tó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìndà, ó ń sá lọ. Kò sì padà sẹ́yìn. (Allāhu sọ pé:) Mūsā, má ṣe páyà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kì í páyà lọ́dọ̀ Mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí,[1] lẹ́yìn náà tí ó yí i padà sí rere lẹ́yìn aburú. Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTi ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ. Ó sì máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe ti aburú. (Èyí wà) nínú àwọn àmì mẹ́sàn-án (tí o máa mú lọ) bá Fir‘aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn àmì Wa tó fojú hàn kedere sì dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n fi àbòsí àti ìgbéraga takò ó, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni. Nítorí náà, wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ti rí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fún (Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n ní ìmọ̀. Àwọn méjèèjì sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún wa ní oore àjùlọ lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) Sulaemọ̄n sì jogún (Ànábì) Dāwūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi ohùn ẹyẹ mọ̀ wá. Wọ́n sì fún wa nínú gbogbo n̄ǹkan.[1] Dájúdájú èyí, òhun ni oore àjùlọ pọ́nńbélé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì kó jọ fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú àlùjànnú, ènìyàn àti ẹyẹ. A sì ń kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń bá a rìn káàkiri
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí wọ́n fi dé àfonúfojì àwọn àwúrèbe. Àwúrèbe kan sì wí pé: “Ẹ̀yin àwúrèbe, ẹ wọ inú ilé yín lọ, kí (Ànábì) Sulaemọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ má baà tẹ̀ yín rẹ́ mọ́lẹ̀. Wọn kò sì níí furamọ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) rẹ́rìn-ín músẹ́, ẹ̀rín pa á nítorí ọ̀rọ̀ (àwúrèbe náà). Ó sọ pé: “Olúwa mi, fi mọ̀ mí bí mo ṣe máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí O fi ṣe ìdẹ̀ra fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì. (Fi mọ̀ mí) bí mo ṣe máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Pẹ̀lú àánú Rẹ, fi mí sáààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni rere.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ yẹ àwọn ẹyẹ wò, ó sì sọ pé: “Nítorí kí ni èmi kò ṣe rí ẹyẹ hudhuda? Àbí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí kò wá ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú mo máa jẹ ẹ́ níyà líle, tàbí kí n̄g dúńbú rẹ̀, tàbí kí ó mú ẹ̀rí tó yanjú wá fún mi.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Sulaemọ̄n) kò dúró pẹ́ (títí ó fi dé), ó sì wí pé: “Mo mọ n̄ǹkan tí o ò mọ̀. Mo sì mú ìró kan tó dájú wá bá ọ láti ìlú Saba’i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi bá obìnrin kan (ní ìlú Saba’i), tó ń jọba lé wọn lórí. Wọ́n fún un ní gbogbo n̄ǹkan. Ó sì ní ìtẹ́ ńlá kan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMo sì bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún òòrùn lẹ́yìn Allāhu. Aṣ-ṣaetọ̄n sì ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (òdodo). Nítorí náà, wọn kò sì mọ̀nà.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Aṣ-ṣaetọ̄n ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn) torí kí wọ́n má lè forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tó ń mú ohùn tó pamọ́ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ jáde, Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ ńlá.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “A máa wòye bóyá òdodo l’o sọ tàbí o wà nínú àwọn òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMú ìwé mi yìí lọ, kí o jù ú sí wọn. Lẹ́yìn náà, kí o takété sí wọn, kí o sì wo ohun tí wọn yóò dá padà (ní èsì).”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, dájúdájú wọ́n ti ju ìwé alápọ̀n-ọ́nlé kan sí mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó wá láti ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n. Dájúdájú ó (sọ pé) “Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ má ṣègbéraga sí mi, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi (láti di) mùsùlùmí.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì í gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan títí ẹ máa fi jẹ́rìí sí i.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Alágbára ni àwa. Akọni ogun sì tún ni wá. Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọ̀rọ̀ wà. Nítorí náà, wòye sí ohun tí o máa pa láṣẹ.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Bilƙīs) wí pé: “Dájúdájú àwọn ọba, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ìlú kan, wọn yóò bà á jẹ́. Wọn yó sì sọ àwọn ẹni abiyì ibẹ̀ di ẹni yẹpẹrẹ. Báyẹn ni wọ́n máa ń ṣe.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú mo máa fi ẹ̀bùn kan ránṣẹ́ sí wọn. Mo sì máa wo ohun tí àwọn ìránṣẹ́ yóò mú padà (ní èsì).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí (ìránṣẹ́) dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n, ó sọ pé: “Ṣé ẹ máa fi owó ràn mí lọ́wọ́ ni? Ohun tí Allāhu fún mi lóore jùlọ sí ohun tí Ó fún yín. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin tún ń yọ̀ lórí ẹ̀bùn yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniPadà sí ọ̀dọ̀ wọn. Dájúdájú à ń bọ̀ wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lè kojú rẹ̀. Dájúdájú a máa mú wọn jáde kúrò nínú (ìlú wọn) ní ẹni yẹpẹrẹ, tí wọn yó sì di ẹni àbùkù.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èwo nínú yín l’ó máa gbé ìtẹ́ (Bilƙīs) wá bá mi, ṣíwájú kí wọ́n tó wá bá mi (láti di) mùsùlùmí.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni‘Ifrīt nínú àwọn àlùjànnú sọ pé: “Èmi yóò gbe wá fún ọ ṣíwájú kí o tó dìde kúrò ní ibùjókòó rẹ. Dájúdájú èmi ni alágbára, olùfọkàntán lórí rẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ìmọ̀ kan láti inú tírà wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò gbé e wá fún ọ ṣíwájú kí o tó ṣẹ́jú.” Nígbà tí ó rí i tí ó dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí wà nínú oore àjùlọ Olúwa mi láti fi dán mi wò bóyá mo máa dúpẹ́ tàbí mo máa ṣàì moore. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́ (fún Allāhu), ó dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàìmoore, dájúdájú Olúwa mi ni Ọlọ́rọ̀, Alápọ̀n-ọ́nlé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Ẹ pa á lójú dà fún un sí ìrísí mìíràn tí kò fi níí dá a mọ̀, kí á wò ó bóyá ó máa dá a mọ̀ tàbí ó máa wà nínú àwọn tí kò níí dá a mọ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí (Bilƙīs) dé, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé bí ìtẹ́ rẹ ṣe rí nìyí?” Ó wí pé: "Ó dà bí ẹni pé òhun ni." (Ànábì Sulaemọ̄n sì sọ pé): “Wọ́n ti fún wa ní ìmọ̀ ṣíwájú Bilƙīs. A sì jẹ́ mùsùlùmí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tó ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu sì ṣẹ́rí rẹ̀ (kúrò níbi jíjọ́sìn fún Allāhu). Dájúdájú ó wà nínú ìjọ aláìgbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ fún un pé: “Wọ inú ààfin.” Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni.” (Bilƙīs) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti ránṣẹ́ sí ìjọ Thamūd. (A rán) arákùnrin wọn, Sọ̄lih (níṣẹ́ sí wọn), pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu.” Nígbà náà ni wọ́n pín sí ìjọ méjì, tó ń bára wọn jiyàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá (ìyà) aburú pẹ̀lú ìkánjú ṣíwájú (ohun) rere (tó yẹ kí ẹ mú ṣe níṣẹ́)? Ẹ kò ṣe tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu nítorí kí Wọ́n lè ṣàánú yín?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “A rí àmì aburú láti ọ̀dọ̀ rẹ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ.” (Ànábì Sọ̄lih) sọ pé: “Àmì aburú yín wà (nínú kádàrá yín) lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì rí bí ẹ ṣe rò ó àmọ́ ìjọ aládàn-ánwò ni yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ènìyàn mẹ́sàn-án kan sì wà nínú ìlú, tí wọ́n ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣàtúnṣe.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí (fúnra wọn) pé: “Kí á dìjọ fí Allāhu búra pé dájúdájú a máa lọ bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní alẹ́ (láti pa á). Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa sọ fún ẹbí rẹ̀ pé ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣojú wa. Dájúdájú olódodo sì ni àwa.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n déte gan-an, Àwa náà sì déte gan-an, wọn kò sì fura.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWo bí àtubọ̀tán ète wọn ti rí. Dájúdájú A pa àwọn àti ìjọ wọn run pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ìwọ̀nyẹn ni ilé wọn. Ó tí di ilé ahoro nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó nímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA gba àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo là, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(A tún fi iṣẹ́ ìmísí rán Ànábì) Lūt. (Rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé iṣẹ́ aburú ni ẹ óò máa ṣe ni, ẹ sì ríran?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín ni) dípò àwọn obìnrin? Àní sẹ́, òpè ènìyàn ni yín.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ohun kan tí ìjọ rẹ̀ fọ̀ ní èsì tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ lé àwọn ènìyàn Lūt jáde kúrò nínú ìlú yín. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn tó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ ọ́ pé ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Kí àlàáfíà máa bá àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tí Ó ṣà lẹ́ṣà. Ṣé Allāhu l’Ó lóore jùlọ ni tàbí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó lóore jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sọ omi kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀, tí A sì fi omi náà hu àwọn ọgbà oko tí ó dára jáde? Kò sì sí agbára fún yín láti mu igi rẹ̀ hù jáde. Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Rárá, ìjọ tó ń ṣẹbọ sí Allāhu ni wọ́n ni.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ibùgbé, tí Ó fi àwọn odò sáààrin rẹ̀, tí Ó fi àwọn àpáta gbagidi sínú ilẹ̀, tí Ó sì fi gàgá sáààrin ibúdò méjèèjì? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹni tí ara ń ni nígbà tí ó bá pè É, tí Ó sì máa gbé aburú kúrò fún un, tí Ó sì ń ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Díẹ̀ ni ohun tí ẹ̀ ń lò nínú ìrántí!
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń tọ yín sọ́nà nínú àwọn òkùnkùn orí ilẹ̀ àti inú ibúdò, tí Ó tún ń fi atẹ́gùn ránṣẹ́ ní ìró ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Allāhu ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí Ó máa dá a padà (lẹ́yìn ikú), tí Ó sì ń pèsè fún yín láti sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àfi Allāhu. Àti pé wọn kò sì mọ àsìkò wo ni A máa gbé àwọn òkú dìde.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, ìmọ̀ wọn máa kẹ́sẹjá ní ọ̀run (orí wọn máa pé ní ọ̀run nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ (báyìí). Àní sẹ́, wọ́n fọ́jú nípa rẹ̀ ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé nígbà tí àwa àti àwọn bàbá wa bá ti di erùpẹ̀, ṣé (nígbà náà ni) wọn yóò mú wa jáde?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú tí ṣe àdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń dá ní ète kó ìnira bá ọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ó lè jẹ́ pé apá kan ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ti súnmọ́ yín tán.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ mà ni Ọlọ́lá lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kì í dúpẹ́ (fún Un).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Ó kúkú mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó hàn kedere.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān yìí yóò máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu sí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú ìdájọ́ Rẹ̀. Òun ni Alágbára, Onímọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, gbáralé Allāhu. Dájúdájú ìwọ wà lórí òdodo pọ́nńbélé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́ nítorí pé, àwọn ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ọ̀rọ̀ náà bá kò lé wọn lórí, A máa mú ẹranko kan jáde fún wọn láti inú ilẹ̀, tí ó máa bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú àwọn ènìyàn kì í ní ìmọ̀ àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé (rántí) ọjọ́ tí A óò kó ìjọ kan jọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn tó ń pe àwọn āyah Wa ní irọ́. A ó sì kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn tí wọ́n máa tẹ̀lé ara wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTítí (di) ìgbà tí wọ́n bá dé (tán), (Allāhu) yóò sọ pé: “Ṣé ẹ pe àwọn āyah Mi ní irọ́, tí ẹ̀yin kò sì ní ìmọ̀ kan nípa rẹ̀ (tí ẹ lè fi já a nírọ́)? Tàbí kí ni ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ (nílé ayé)?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A dá òru nítorí kí wọ́n lè sinmi nínú rẹ̀, (A sì dá) ọ̀sán (nítorí kí wọ́n lè) ríran? Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo, gbogbo ẹni tí ó wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ yó sì jáyà tó máa mú wọn kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Gbogbo ẹ̀dá l’ó sì máa yẹpẹrẹ wá bá Allāhu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniO sì máa rí àwọn àpáta, tí o lérò pé n̄ǹkan gbagidi tó dúró sojú kan náà ni, tí ó máa rin ìrìn ẹ̀ṣújò.[1] (Ìyẹn jẹ́) iṣẹ́ Allāhu, Ẹni tí Ó ṣe gbogbo n̄ǹkan dáadáa. Dájúdájú Alámọ̀tán ni nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá dé pẹ̀lú iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni rere tó lóore ju èyí tó ṣe. Àwọn sì ni olùfàyàbalẹ̀ nínú ìjáyà ọjọ́ yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá sì dé pẹ̀lú iṣẹ́ aburú, A sì máa da ojú wọn bolẹ̀ nínú Iná. Ǹjẹ́ A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí wọ́n pa mí ní àṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Olúwa Ìlú yìí, Ẹni tí Ó ṣe é ní àyè ọ̀wọ̀. TiRẹ̀ sì ni gbogbo n̄ǹkan. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kí èmi máa ké al-Ƙur’ān. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkìlọ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu.” (Allāhu) yóò fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ẹ̀yin yó sì mọ̀ wọ́n. Olúwa rẹ kò sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.