الصافات
As-Saffat
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo aṣ-Ṣaetọ̄n olóríkunkun.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniBi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn)[1] tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
- Abu Rahimah Mikael Aykyunilẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni kò jẹ́ kí ẹ ran ara yín lọ́wọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniApá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bi ara wọn léèrè ìbéèrè.[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ènìyàn) wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà).”[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn àlùjànnú) wí pé: “Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu ààlà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà. (Wọ́n dìjọ máa wà nínú Iná.)
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé “Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”, wọn yóò máa ṣègbéraga.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ń wí pé: “Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTi àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ láti inú odò kan tó ń ṣàn káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFunfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn tó máa mu ún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n dà bí ẹyin tí wọn kò ì bó èèpo rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniApá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ (sì) sọ pé: “Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa kò sá níí kú mọ́ báyìí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈso rẹ̀ dà bí orí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí ó dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì sọ pé: “Dájúdájú ó rẹ̀ mí.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni ó ṣe yín tí ẹ kò sọ̀rọ̀?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìfaradà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: “Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú[1] (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunio kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniBi wọ́n léèrè wò pé: “Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni“Allāhu bímọ.” Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú ń wí pé:
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni“Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.