ص
Sad
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.)[1] Allāhu fi al-Ƙur’ān tí ó kún fún ìrántí bura.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSíbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) nígbà tí kò sí ibùsásí kan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni òpìdán, òpùrọ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn aṣíwájú nínú wọn sì lọ (káà kiri láti wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn wọn) pé: “Ẹ máa bá (ìbọ̀rìṣà) lọ, kí ẹ sì dúró ṣinṣin ti àwọn òrìṣà yín. Dájúdájú èyí (jíjẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Allāhu) ni n̄ǹkan tí wọ́n ń gbàlérò (láti fi pa àwọn òrìṣà yín run).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa kò gbọ́ èyí nínú ẹ̀sìn ìkẹ́yìn (ìyẹn, ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄)[1]. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àdápa irọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé Wọ́n sọ (tírà) Ìrántí kalẹ̀ fún un láààrin wa ni?” Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa (tírà) Ìrántí Mi (tí Mo sọ̀kalẹ̀ ni). Rárá, wọn kò tí ì tọ́ ìyà Mi wò ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí tiwọn ni àwọn ilé ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ, Alágbára, Ọlọ́rẹ?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí tiwọn ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin méjèèjì? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wọn wá àwọn ọ̀nà láti fi gùnkè wá (bá Wa).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA máa ṣẹ́gun ọmọ ogun tó wà níbẹ̀ yẹn nínú ọmọ ogun oníjọ.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti Fir‘aon, eléèkàn, wọ́n pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ Thamūd, ìjọ Lūt àti àwọn ará ’Aekah, àwọn wọ̀nyẹn (tún ni) àwọn ìjọ (tó pe òdodo ní irọ́).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹnì kan nínú wọn tí kò pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà Mi sì kò lé wọn lórí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyí kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan, tí kò níí ní ìdádúró.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Olúwa wa, yára fi ìwé iṣẹ́ wa (àti ìpín ẹ̀san wa) lé wa lọ́wọ́ ṣíwájú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ. Kí o sì ṣèrántí ìtàn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) Dāwūd, alágbára. Dájúdájú ó jẹ́ olùronúpìwàdà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa tẹ àwọn àpáta lórí ba tí wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ (fún Allāhu) ní ìrọ̀lẹ́ àti nígbà tí òòrùn bá yọ (ní òwúrọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti àwọn ẹyẹ náà, A kó wọn jọ fún un. Ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ (láti ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A fún ìjọba rẹ̀ ní agbára. A sì fún un ní ipò Ànábì àti ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ àti ìdájọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ìró àwọn oníjà ti dé ọ̀dọ̀ rẹ; nígbà tí wọ́n pọ́n ògiri ilé ìjọ́sìn?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Dāwūd, ẹ̀rù wọn bà á. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Oníjà méjì (ni wá). Apá kan wa tayọ ẹnu-ààlà sí apá kan. Nítorí náà, fi òdodo dájọ́ láààrin wa. Má ṣàbòsí. Kí o sì tọ́ wa sí ọ̀nà tààrà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí ni arákùnrin mi. Ó ní abo ewúrẹ́ mọ́kàndín-lọ́gọ́rùn-ún. Èmi sì ní abo ewúrẹ́ ẹyọ kan. Ó sì sọ pé: “Fà á lé mi lọ́wọ́ (Fi mí ṣe alámòójútó rẹ̀). Ó sì borí mi nínú ọ̀rọ̀.” (Ó fi ọ̀rọ̀ tirẹ̀ borí ọ̀rọ̀ tèmi.)
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì Dāwūd) sọ pé: “Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-ààlà lórí apá kan àfi àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n.” (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A ṣàforíjìn ìyẹn fún un. Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un lọ́dọ̀ Wa.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) Dāwūd, dájúdájú Àwa ṣe ọ́ ní àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, fi òdodo dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú nítorí kí ó má baà ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń sọnù kúrò nínú ẹ̀sìn Allāhu, ìyà líle wà fún wọn nítorí pé, wọ́n gbàgbé Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò fi irọ́ ṣẹ̀dá sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì. (Irọ́), ìyẹn ni èrò ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (sí Wa). Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Iná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kí Á ṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere bí (A ó ti ṣe) àwọn òbìlẹ̀jẹ́ lórí ilẹ̀? Tàbí ṣé kí Á ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Mi bí A ó ti ṣe) àwọn aṣebi?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Èyí ni) Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa àwọn āyah rẹ̀ àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA fi (Ànábì) Sulaemọ̄n ta (Ànábì) Dāwūd lọ́rẹ. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sọ́dọ̀ (Allāhu) ni (nípa ìronúpìwàdà).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹṣin akáwọ́ọ̀jà-lérí asárétete wá bá a ní ìrọ̀lẹ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunió sọ pé: “Dájúdájú èmi fẹ́ràn ìfẹ́ ohun rere (ìyẹn, àwọn ẹṣin náà) dípò ìrántí Olúwa Mi (ìyẹn, ìrun ‘Asr) títí òòrùn fi wọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ dá wọn padà sọ́dọ̀ mi.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà gé wọn ní ẹsẹ̀ àti ní ọrùn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sọ pé: “Olúwa mi, forí jìn mí. Kí O sì ta mí ní ọrẹ ìjọba kan èyí tí kò níí tọ́ sí ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn mi. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Ọlọ́rẹ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A tẹ atẹ́gùn ba fún un. Ó ń fẹ́ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn síbi tí ó bá fẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú; gbogbo àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn awakùsà (ni A tẹ̀ ba fún un).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti àwọn (àlùjànnú) mìíràn tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mọ́lẹ̀ (A tẹ̀ wọ́n ba fún un).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání[1] láì níí ní ìṣírò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un ní ọ̀dọ̀ Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢèrántí ẹrúsìn Wa, (Ànábì)’Ayyūb. Nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ (pé): “Dájúdájú aṣ-Ṣaetọ̄n ti kó ìnira (àìsàn) àti ìyà bá mi.”[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Mọlāika sọ fún un pé): “Fi ẹsẹ̀ rẹ janlẹ̀. Èyí ni omi ìwẹ̀ tútù àti omi mímu (fún ìwòsàn rẹ).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ.[1] Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára àti olùríran (nípa ẹ̀sìn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan, (òhun ni) ìrántí Ilé náà (ilé Ìkẹ́yìn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢèrántí (àwọn Ànábì) ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniIná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ìjọ kan tó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) “Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn.” Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: “Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fún yín. Ẹ̀yin l’ẹ pè wá síbi èyí (tó bí Iná).” Ó sì burú ní ibùgbé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n (tún) wí pé: “Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n tún wí pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a kò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l’a ò fi rí wọn nínú Iná)?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “(al-Ƙur’ān) ni ìró ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí Mo bá ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un, kí ẹ forí kanlẹ̀ kí i.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ’Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “’Iblīs, kí l’ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ wí pé: “Èmi lóore jù ú lọ; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara ẹrẹ̀.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé, dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(aṣ-Ṣaetọ̄n) wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ̀.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(aṣ-Ṣaetọ̄n) wí pé: “Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo) nínú wọn.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sọ pé: “Òdodo (ni ìbúra Mi), òdodo sì ni Èmi ń sọ, (pé)
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú Mo máa fi ìwọ àti gbogbo àwọn tó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn kún inú iná Jahanamọ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Èmi kò sì sí nínú àwọn onítàn-àròsọ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ẹ máa mọ ìró rẹ̀ (sí òdodo) láìpẹ́.