غافر

Ghafir

Sūrah 40 · ti Mọkkah · āyah 85 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 60

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniHā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí Mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: “Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): “Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére èyí tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni tó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): “Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì.[1] Nítorí náà, a jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àfi ẹni tó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) Ẹni tó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀[1] nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): “Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní?” Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ṣèkìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó súnmọ́ (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde). Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé, àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí tó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunisí Fir‘aon àti Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: “Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā).”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀.” Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú ìṣìnà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFir‘aon wí pé: “Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan tó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: “Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, “Allāhu ni Olúwa mi.” Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fún yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, tí ẹ ga jùlọ lórí ilẹ̀ náà (ìyẹn ilẹ̀ Misrọ). Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?” Fir‘aon wí pé: “Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà tó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín;
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIrú ìṣe (ìparun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn tó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fún yín.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: “Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFir‘aon wí pé: “Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé, dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́.” Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn mi, ìgbádùn lásán ni ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo,[1] àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún wọn nínú rẹ̀ láì níí ní ìṣírò.[2]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un.[1] Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-ààlà, àwọn ni èrò inú Iná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fún yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): “Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná tó le jùlọ.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣègbéraga máa wí pé: “Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó wà nínú Iná tún máa wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: “Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n yóò sọ pé: “Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín bí?” Wọ́n á wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, (wọ́n mú un wá).” Wọ́n máa sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ[1] ní ìrọ̀lẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAfọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn tó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi,[1] wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn tó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ibùgbé. Ó sì ṣe sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o kò wòye sí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní irọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunisínú omi tó gbóná parí. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ fún wọn pé: “Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà?”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni“(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?” Wọ́n á wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́ àti nítorí pé, ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fún yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn àǹfààní (mìíràn) wà fún yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn tó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ sì ń fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò?[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀(fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun tó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌgbàgbọ́ wọn kò sì ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.