فصلت

Fussilat

Sūrah 41 · ti Mọkkah · āyah 54 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 61

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniHā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌmísí kan (nìyí) tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTírà kan ni tí wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀,[1] (ó ń jẹ́) al-Ƙur’ān (tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ní) èdè Lárúbáwá fún ìjọ tó nímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì wí pé: “Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í (nínú ìjọ́sìn), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tí kò yọ Zakāh, àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín tí kò níí dáwọ́ dúró ń bẹ fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ Rẹ̀ (tí ẹ̀ ń bọ wọ́n)?” Ìyẹn (Ẹlẹ́dàá ilẹ̀) sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin.[1] (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: “Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀.” Àwọn méjèèjì sọ pé: “A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀.”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì parí (ìṣẹ̀dá) rẹ̀ sí sánmọ̀ méje fún ọjọ́ méjì. Ó sì fi iṣẹ́ sánmọ̀ kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sínú rẹ̀. A sì fi àwọn àtùpà (ìràwọ̀) ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ àti ààbò (fún un). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá gbúnrí, sọ pé: “Èmi ń ṣèkìlọ̀ iná láti ojú sánmọ̀ irú iná láti ojú sánmọ̀ tó gbá ìjọ ‘Ād àti Thamūd mú fún yín ni.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn,[1] (wọ́n sọ) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Allāhu.” Wọ́n wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: “Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?” Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni? Wọ́n sì ń tako àwọn āyah Wa!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ìjọ Thamūd, A ṣàlàyé ìmọ̀nà fún wọn,[1] ṣùgbọ́n wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àìríran dípò ìmọ̀nà. Nítorí náà, ìyà iná láti ojú sánmọ̀ tó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá gbá wọn mú nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì gba àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu) là.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí wọ́n máa kó àwọn ọ̀tá Allāhu jọ síbi Iná, wọn yó sì kó àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn papọ̀ mọ́ àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: “Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?” Wọ́n yóò sọ pé: “Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l’Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin kò lè para yín mọ́ (kúrò níbi ẹ̀ṣẹ̀, nítorí) kí ìgbọ́rọ̀ yín, ìríran yín àti awọ ara yín má fi lè jẹ́rìí le yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ lérò pé dájúdájú Allāhu kò mọ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn, èrò ọkàn yín tí ẹ lérò sí Olúwa yín ló kó ìparun ba yín. Ẹ sì di ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá ṣe sùúrù (fún ìyà), Iná kúkú ni ibùgbé fún wọn. Tí wọ́n bá sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu (ní àsìkò yìí), wọn kò sí níí wà nínú àwọn tí wọ́n máa rí ìyọ́nú Allāhu gbà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn,[1] tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn[2] àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn[3] ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ tó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí al-Ƙur’ān yìí. Kí ẹ sì sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀ kí ẹ lè borí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí tó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniIná, ìyẹn ni ẹ̀san àwọn ọ̀tá Allāhu. Ilé gbére wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ó jẹ́ ẹ̀san nítorí pé wọ́n ń tako àwọn āyah Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Olúwa wa, fi àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣì wá lọ́nà nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn hàn wá, kí á fi àwọn méjèèjì sí abẹ́ ẹsẹ̀ wa, nítorí kí àwọn méjèèjì lè wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin (sínú ẹ̀sìn títí di ọjọ́ ikú wọn), àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa ni ọ̀rẹ́ yín nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní ọ̀run. Ohun tí ẹ̀mí yín ń fẹ́ ti wà fún yín nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún sì ti wà nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ jẹ́ n̄ǹkan ìgbàlejò (fún yín) láti ọ̀dọ̀ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNíbi ọ̀rọ̀ sísọ, ta ni ó dára ju ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: “Dájúdájú èmí wà nínú àwọn mùsùlùmí?”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú).[1] Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA ku n yín) sìn títí di ọjọá hu pátápátá.n ní Ọjọ́ Àjíǹde.́ wọn gbàgbé Allāhu.ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn tó ṣe sùúrù. A kò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé tí èròkérò kan láti ọ̀dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n bá fẹ́ ṣẹ́ ọ lórí (kúrò níbi ìwà rere yìí), sádi Allāhu (fi Allāhu wá ìṣọ́rí). Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ kò gbọ́dọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni tó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá sì ṣègbéraga, àwọn tó wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní alẹ́ àti ní ọ̀sán; wọn kò sì kágara.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó talẹ̀ jí, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń darí àwọn āyah Wa kọ ọ̀nà òdì,[1] wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà tó lágbára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀.[1] Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé A ṣe al-Ƙur’ān ní n̄ǹkan kíké ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá ni, wọn ìbá wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n ṣe àlàyé àwọn āyah rẹ̀?” Báwo ni al-Ƙur’ān ṣe lè jẹ́ èdè mìíràn (yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá), nígbà tí Ànábì (Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) jẹ́ Lárúbáwá? Sọ pé: “Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìwòsàn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Àwọn tí kò sì gbàgbọ́, èdídí wà nínú etí wọn ni. Fọ́júǹǹfọ́jú sì wà nínú ojú wọn sí (òdodo al-Ƙur’ān). Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n sì ń pè (síbi òdodo al-Ƙur’ān) láti àyè tó jìnnà.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa-ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: “Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?”[1] Wọ́n á wí pé: “Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé, O ní akẹgbẹ́.)”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1] Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé, kò sí ibùsásí kan fún àwọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈnìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.” Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà tó nípọn tọ́ wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)” Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo)!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká.