الذاريات

Adh-Dhariyat

Sūrah 51 · ti Mọkkah · āyah 60 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 67

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi atẹ́gùn tó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ ní títu-jáde tààrà búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn ẹ̀ṣújò tó ru òjò tó wúwo búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn mọlāika tó ń pín n̄ǹkan tí Ó ti pín fún ẹ̀dá búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ẹ̀san iṣẹ́ máa ṣẹlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu tún fi sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ tó gún régé búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ tó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni fún àwọn òpùrọ́;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tí wọ́n wà nínú àìmọ̀kan tó gbópọn tí wọ́n ti gbàgbéra.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunití wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ kò ríran ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniArísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín wà nínú sánmọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Òun náà sọ pé: “Àlàáfíà (fún yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù tó ní ọ̀rá (tí wọ́n ti yangbẹ).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, ìbẹ̀rù wọn sì mú un.[1]. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe páyà.” Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, ìyàwó rẹ̀ wọlé pẹ̀lú igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: “Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.”
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ti fi àmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A mú àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò sì rí nínú (ìlú náà) yàtọ̀ sí ilé kan tó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn tó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti kẹ̀yìn sí òdodo. Ó sì wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí).”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kí ó sọ ọ́ di n̄ǹkan tó kẹfun.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ arúfin.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni Alágbára (tí a mú un tóbi).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. (Àwa sì ni) olùtẹ́-ilẹ̀ sílẹ̀ tó dára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn tó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè ni.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-ààlà ni wọ́n ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe ẹni tí A máa bá wí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn tó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.