الطور
At-Tur
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àpáta Tūr búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi Tírà tí wọ́n kọ n̄ǹkan sínú rẹ̀ búra .
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n kọ̀ ọ́) sínú n̄ǹkan ìkọ̀wé tí wọ́n tẹ́ ojú rẹ̀ sílẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi Ilé tí àwọn mọlāika ń wọnú rẹ̀ ní ojoojúmọ́ nínú sánmọ̀ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀) búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi agbami odò tí wọ́n máa mú iná jáde nínú rẹ̀ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹni tí ó máa dènà rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàpáta sì máa rìn lọ dànù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn tó pe òdodo ní irọ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò máa tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé idán ni èyí ni tàbí ẹ̀yin kò ríran?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ kò fara dà á, bákan náà ni fún yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn kúrò níbi ìyà iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A kò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa dúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniApá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò sọ pé: “Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa máa ń páyà láààrin àwọn ènìyàn wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá kúrò níbi ìyà Iná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ń wí pé: “Eléwì kan tí à ń retí àpadàsí aburú fún ni.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ọpọlọ wọn ló ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn ilé ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ní àkàbà kan tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀)? Kí ẹni tí ó ń bá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ mú ẹ̀rí tó yanjú wá?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá rí apá kan nínú sánmọ̀ tó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn tó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ní alẹ́ àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán[1], ṣàfọ̀mọ́ fún Un.