الواقعة
Al-Waqi'ah
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-
- Abu Rahimah Mikael Aykyunió máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni- wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn
- Abu Rahimah Mikael Aykyunipẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ibòji tó gbòòrò,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniolólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunikò tutù, kò sì dára.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniIkùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniláti yí irú yín padà (láti inú erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì ṣẹ̀dá yín (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ (nínú àwọn ìrísí).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunikí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunin̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti wíwọ inú iná Jẹhīm.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.