الرحمن
Ar-Rahman
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀjọkẹ́-ayé,
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣẹ̀dá ènìyàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)
- Abu Rahimah Mikael Aykyunipé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi òṣùwọ̀n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniIlẹ̀, (Allāhu) gbé e kalẹ̀ (sí abẹ́ sánmọ̀ fún àwọn ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti èso onípòpórò àti olóòórùn dídùn (wà lórí ilẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ tó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-ààlà (rẹ̀ láààrin ara wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTi (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro tó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ máa tán.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOjú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ kò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa ju ahọ́n iná àti èéfín (tàbí oje idẹ) iná lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì níí lè ranra yín lọ́wọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa gbígbá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn kò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè ní irọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi tó gbóná parí.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni tó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi tó kún fún àwọn èso oríṣiríṣi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOdò méjì tó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọgbà méjèèjì.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán tó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn (nípa ẹwà àti dídára wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌgbà Ìdẹ̀ra méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn odò méjì tó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra náà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈnìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ tó dára.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.