المجادلة
Al-Mujadila
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ (obìnrin) tó ń bá ọ ṣe àríyànjiyàn nípa ọkọ rẹ̀, tí ó sì ń ṣàròyé fún Allāhu. Allāhu sì ń gbọ ìsọ̀rọ̀gbèsì ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn nínú yín, àwọn ìyàwó kì í ṣe ìyá wọn. Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ìyá wọn bí kò ṣe ìyá tí ó bí wọn lọ́mọ.[1] Dájúdájú wọ́n ń sọ aburú nínú ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ irọ́. Dájúdájú Allāhu ni Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò níbi ohun tí wọ́n sọ, wọn máa tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó lè súnmọ́ ara wọn. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí kò bá rí (ẹrú), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó lè súnmọ́ ara wọn. Ẹni tí kò bá ní agbára (ààwẹ̀), ó máa bọ́ ọgọ́ta tálíkà. Ìyẹn nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀dá. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, A óò yẹpẹrẹ wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe yẹpẹrẹ àwọn tó ṣíwájú wọn. A kúkú ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, àwọn sì gbàgbé rẹ̀. Allāhu sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ni? Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn. Wọ́n kéré sí ìyẹn, wọ́n tún pọ̀ (ju ìyẹn) àfi kí Ó wà pẹ̀lú wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà.[1] Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o kò rí àwọn tí A kọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ fún, lẹ́yìn náà tí wọ́n tún padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Wọ́n ń bára wọn sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Nígbà tí wọ́n bá sì dé ọ̀dọ̀ rẹ, wọn yóò kí ọ ní kíkí tí Allāhu kò fi kí ọ. Wọ́n sì ń wí sínú ẹ̀mí wọn pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Allāhu jẹ wá níyà lórí ohun tí à ń wí (ní ìkọ̀kọ̀)!” Iná Jahanamọ máa tó wọn. Wọ́n máa wọ inú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Ẹ bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (burúkú) ń wá láti ọ̀dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n nítorí kí ó lè kó ìbànújẹ́ bá àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá wọn àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá sọ fún yín pé kí ẹ gbara yín láyè nínú àwọn ibùjókòó, ẹ gbara yín láyè. Allāhu yóò f’àyè gbà yín. Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: “Ẹ dìde (síbi iṣẹ́ rere).” Ẹ dìde (sí i). Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá bá Òjíṣẹ́ sọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ,[1] ẹ fi ọrẹ títa ṣíwájú ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín. Ó sì fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Tí ẹ ò bá sì rí (ọrẹ), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ̀ ń páyà (òṣì) níbi kí ẹ máa ti ọrẹ ṣíwájú àwọn ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín ni? Nígbà tí ẹ ò ṣe é, Allāhu sì gba ìronúpìwàdà yín. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò rí àwọn (ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) tí wọ́n mú ìjọ kan tí Allāhu bínú sí ní ọ̀rẹ́ (ìyẹn àwọn yẹhudi)? Wọn kì í ṣe ara yín, (àwọn munāfiki kì í ṣe ara ẹ̀yin mùsùlùmí) wọn kì í sì ṣe ara wọn (àwọn munāfiki kì í sì ṣe ara àwọn yẹhudi). Wọ́n yó sì máa búra lórí irọ́, wọ́n sì mọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu ti pèsè ìyà líle dè wọ́n. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n fi ìbúra wọn ṣe ààbò; wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Nítorí náà, ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde pátápátá, wọn yó sì máa búra fún Un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń búra fún yín. Wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ti rí n̄ǹkan ṣe. Gbọ́! Dájúdájú àwọn gan-an ni òpùrọ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniaṣ-Ṣaetọ̄n jẹgàba lé wọn lórí. Ó sì mú wọn gbàgbé ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ aṣ-Ṣaetọ̄n. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ aṣ-Ṣaetọ̄n, àwọn ni ẹni òfò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn olùyẹpẹrẹ jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu kọ ọ́ pé: “Dájúdájú Mo máa borí; Èmi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniO ò níí rí ìjọ kan tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kódà kí wọ́n jẹ́ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ìbátan wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ti kọ ìgbàgbọ́ òdodo sínú ọkàn wọn. Allāhu sì fi ẹ̀rí òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.[1] Ó sì máa mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Allāhu. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùjèrè.[2]