الحشر
Al-Hashr
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Ẹni tí Ó mú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà[1] jáde kúrò nínú ilé wọn fún àkọ́kọ́ àkójọ (wọ́n sínú ìlú Ṣām). Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò ti lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ti kọ ìjáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah lé àwọn onítírà lórí ni, dájúdájú (Allāhu) ìbá jẹ wọ́n níyà nílé ayé. Ìyà Iná sì tún wà fún wọn ní ọ̀run.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu, dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin kò níí ge igi dàbínù kan tàbí kí ẹ fi sílẹ̀ kí ó dúró sórí gbòǹgbò rẹ̀, (àfi) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè dójú ti àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ni.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ wọn fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ẹ kò gbé ẹṣin àti ràkúnmí sáré fún (ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni). Ṣùgbọ́n Allāhu yóò máa fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní agbára lórí ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (ó jẹ́) ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ àti ti àwọn ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tálíkà àti onírìn-àjò (tí agara dá) nítorí kí ó má baá jẹ́ àdápín láààrin àwọn ọlọ́rọ̀ nínú yín. Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fún yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fún yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìkógun náà tún wà fún) àwọn aláìní, (ìyẹn,) al-Muhājirūn, àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ilé wọn àti níbi dúkìá wọn, tí wọ́n sì ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí wọ́n sì ń ṣàrànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olódodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ òdodo ṣíwájú wọn,[1] wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn (ní ìlú Mọdīnah). Wọn kò sì ní bùkátà kan nínú igbá-àyà wọn sí n̄ǹkan tí wọ́n bá fún wọn. Wọ́n sì ń gbé àjùlọ fún wọn lórí ẹ̀mí ara wọn, kódà kí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ní bùkátà (sí ohun tí wọ́n fún wọn). Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó dé lẹ́yìn wọn ń sọ pé: “Olúwa wa, foríjin àwa àti àwọn ọmọ ìyá wa tó ṣíwájú wa nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Má ṣe jẹ́ kí inúnibíni wà nínú ọkàn wa sí àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o ò rí àwọn tó ṣàgàbà ǹgebè nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń wí fún àwọn ọmọ ìyá wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà, pé “Dájúdájú tí wọ́n bá le yín jáde (kúrò nínú ìlú), àwa náà gbọ́dọ̀ jáde pẹ̀lú yín ni. Àwa kò sì níí tẹ̀lé àṣẹ ẹnì kan lórí yín láéláé. Tí wọ́n bá sì gbé ogun dìde si yín, àwa gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín ni.” Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú tí wọ́n bá lé wọn jáde, wọn kò níí jáde pẹ̀lú wọn.[1] Dájúdájú tí wọ́n bá sì gbógun tì wọ́n, wọn kò níí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ wọn, dájúdájú wọn yóò pẹ̀yìndà (láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ̀yin ni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó lágbára ju Allāhu lọ nínú igbá-àyà wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò lè parapọ̀ dojú ìjà kọ yín àfi (kí wọ́n) wà nínú odi ìlú tàbí (kí wọ́n wà) lẹ́yìn àwọn ògiri. Ogun ààrin ara wọn gan-an le. Ò ń lérò pé wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ ni, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ọkàn wọn wà. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ní làákàyè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀpẹ̀ẹrẹ wọn dà bí àwọn tó ṣíwájú wọn tí kò tí ì pẹ́ lọ títí. Wọ́n tọ́ aburú ọ̀rọ̀ ara wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀpẹ̀ẹrẹ wọn dà bí aṣ-Ṣaetọ̄n nígbà tí ó bá wí fún ènìyàn pé: “Ṣàì gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ (tán), ó máa wí pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Dájúdájú èmi ń páyà Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ìkángun àwọn méjèèjì ni pé, dájúdájú àwọn méjèèjì yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni àwọn méjèèjì nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ̀mí kan sì wòye sí ohun tí ó tì ṣíwájú fún ọ̀la (àlùkìyáámọ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ẹ sì má ṣe dà bí àwọn tó gbàgbé Allāhu. (Allāhu) sì mú wọn gbàgbé ẹ̀mí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni arúfin.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn èrò inú Iná àti àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra kò dọ́gba. Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn ni olùjèrè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé A sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ sórí àpáta ni, dájúdájú o máa rí i tí ó máa wálẹ̀, tí ó máa fọ́ pẹ́tẹpẹ̀tẹ fún ìpáyà Allāhu. Ìwọ̀nyí ni àwọn àkàwé tí À ń fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Òun ni Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọba (ẹ̀dá), Ẹni-mímọ́ jùlọ, Aláìlábùkù, Olùjẹ́rìí-Òjíṣẹ́-Rẹ̀, Olùjẹ́rìí-ẹ̀dá, Alágbára, Olùjẹni-nípá, Atóbi. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Allāhu, Ẹlẹ́dàá, Olùpilẹ̀-ẹ̀dá, Olùyàwòrán-ẹ̀dá. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.