القلم

Al-Qalam

Sūrah 68 · ti Mọkkah · āyah 52 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 2

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNūn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.)[1] Allāhu fi gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà ńlá (ìwà alápọ̀n-ọ́nlé).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLáìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunièwo nínú yín ni aládàn-ánwò (wèrè)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniabúni, alárìnká tó ń sòfófó kiri,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniolùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, ògbólógbòó ẹni ibi (àsáwọ̀[1], ọmọ zina) ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)”.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA máa fi àmì sí i ní góńgórí imú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé, dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò sì ṣe àyàfi pé, “tí Allāhu bá fẹ́”.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀdánwò tó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunipé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunipé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n jí lọ (sí oko wọn) lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa ti ṣìnà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: “Ṣé èmi kò sọ fún yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé “a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu.)”?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniApá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu ààlà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí tó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná?[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí tírà kan wà fún yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunipé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: “Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá.”?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ní (àwọn òrìṣà kan) tí wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Wa? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOjú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, fi Èmi àti ẹni tó ń pe ọ̀rọ̀ yìí ní irọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: “Dájúdájú wèrè mà ni.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.