الحاقة

Al-Haqqah

Sūrah 69 · ti Mọkkah · āyah 52 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 78

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunití wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi![1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniHáà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAgbára mi sì ti parun.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u[1] ni kí ẹ kì í sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ohun tí ẹ ò fojú rí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.