المعارج

Al-Ma'arij

Sūrah 70 · ti Mọkkah · āyah 44 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 79

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunisí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunilọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa bó awọ orí tòró.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunió kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn olùkírun,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunisí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunití wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn[1] búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniláti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOjú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.