المزمل
Al-Muzzammil
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ olùdaṣọbora.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDìde (kírun) ní òru àyàfi fún ìgbà díẹ̀ (ni kí o fi sùn nínú òru rẹ).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLo ìlàjì rẹ̀ tàbí dín díẹ̀ kù nínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí fi kún un. Kí o sì ké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa máa gbé ọ̀rọ̀ tó lágbára fún ọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìdìde kírun lóru, ó wọnú ọkàn jùlọ, ó sì dára jùlọ fún kíké (al-Ƙur’ān).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú iṣẹ́ púpọ̀ wà fún ọ ní ọ̀sán.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRántí orúkọ Olúwa rẹ. Kí o sì da ọkàn kọ Ọ́ pátápátá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àfi Òun. Nítorí náà, mú Un ní Aláfẹ̀yìntì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Pa wọ́n tì ní ìpatì tó rẹwà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniFi Mí dá àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn ọlọ́rọ̀. Kí o sì lọ́ra fún wọn fún ìgbà díẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti Iná Jẹhīm ń bẹ lọ́dọ̀ Wa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOúnjẹ háfunháfun àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro (tún wà fún wọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí ilẹ̀ àti àwọn àpáta yóò máa mì tìtì. Àwọn àpáta sì máa di yanrìn tí wọ́n kójọ tí wọ́n túká.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ̀yin bá ṣàì gbàgbọ́, báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe bẹ̀rù ọjọ́ kan tó máa mú àwọn ọmọdé hewú?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSánmọ̀ sì máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú rẹ̀. Àdéhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa ṣẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà kan tọ̀ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ mọ̀ pé dájúdájú ìwọ ń dìde kírun fún ohun tó kéré sí ìlàta méjì òru tàbí ìlàjì rẹ̀ tàbí ìlàta rẹ̀. Igun kan nínú àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu l’Ó ń ṣòdíwọ̀n òru àti ọ̀sán. Ó sì mọ̀ pé ẹ kò lè ṣọ́ ọ.[1] Nítorí náà, Ó ti dá a padà sí fífúyẹ́ fún yín. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú al-Ƙur’ān. Ó mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò wà nínú yín. Àwọn mìíràn sì ń rìrìn àjò lórí-ilẹ̀, tí wọ́n ń wá nínú oore Allāhu. Àwọn mìíràn sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú rẹ̀. Ẹ kírun (ọ̀ran-an-yàn). Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Ohunkóhun tí ẹ bá tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín nínú ohun rere, ẹ̀yin yóò bá a lọ́dọ̀ Allāhu ní ohun rere àti ní ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀san. Ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.