المدثر

Al-Muddaththir

Sūrah 74 · ti Mọkkah · āyah 56 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 4

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ olùdaṣọbora.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDìde kí o ṣèkìlọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒrìṣà ni kí o jìnnà sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunití kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)[1].
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó wò sùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa jó awọ ara di dúdú.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: “Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ gbọ́! Allāhu fi òṣùpá búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni“Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò wí pé: “Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí ikú fi dé bá wa.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunibí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunitó sá fún kìnìhún?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn.