القيامة
Al-Qiyamah
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá. (À ń jẹ́) Alágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀
- Abu Rahimah Mikael Aykyunini ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, kò sí ibùsásí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniMá ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa wọn ni wọn yóò máa wò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOjúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìparun nílé ayé) ló tọ́ sí ọ jùlọ (lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wọ̀nyẹn). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, (Iná) ló tọ́ sí ọ jùlọ (ní ọ̀run). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?