المرسلات

Al-Mursalat

Sūrah 77 · ti Mọkkah · āyah 50 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 33

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniFún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunitítí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1]