النبإ

An-Naba

Sūrah 78 · ti Mọkkah · āyah 40 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 80

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunièyí tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, rárá sẹ́, wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣe oorun yín ní ìsinmi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún ṣe alẹ́ ní ìbora.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún mọ sánmọ̀ méje tó lágbára sókè yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn gbòlà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé A sọ omi tó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunipẹ̀lú àwọn ọgbà tó kún digbí fún n̄ǹkan oko.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàyàfi omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ẹ̀san tó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́ gan-an.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fún yín bí kò ṣe ìyà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ọgbà oko àti èso àjàrà,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ife ọtí tó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun tó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ tó máa ṣe wẹ́kú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A fi ìyà tó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fún yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà).”