القدر

Al-Qadr

Sūrah 97 · ti Mọkkah · āyah 5 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 25

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÒru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.