العلق
Al-'Alaq
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKé (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKé e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀
- Abu Rahimah Mikael Aykyunifún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.[1]) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí[2] rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).