الزلزلة
Az-Zalzalah
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù tó wúwo nínú rẹ̀ jáde,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniènìyàn yó sì wí pé: “Kí l’ó mú un?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.[1]