العاديات
Al-'Adiyat
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?