النصر
An-Nasr
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀.[1] Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà.