النجم

An-Najm

Sūrah 53 · ti Mọkkah · āyah 62 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 23

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAlágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ní àlàáfíà tó péye, ó sì dúró wámúwámú,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí tó fún un.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌkàn (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kò parọ́ ohun tó rí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun tó rí ni?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ó tún rí i nígbà kejì[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniníbi igi sidirah al-Muntahā,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí ohun tó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOjú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-ààlà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, tó tóbi.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌpín àbòsí nìyẹn nígbà náà.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́ (ìfẹ́-inú). Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan tó bá ń fẹ́!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika tó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Dájúdájú àbá dídá kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌyẹn ni ohun tí wọ́n wọ̀n nínú ìmọ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó mọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́.[1] Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniSọ fún mi nípa ẹni tó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọn kò fún un ní ìró ohun tó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni tó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunipé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun tó ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san tó kún jùlọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniláti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun l’Ó ń fún ẹ̀dá ní ọrọ̀ dúkìá, Ó sì ń ta ẹ̀dá ní òṣì.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìjọ Nūh tó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-ààlà jùlọ;
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìlú tó dojú bolẹ̀ (ìlú Ànábì Lūt), Allāhu ló yẹ̀ ẹ́ lulẹ̀ (láti òkè).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tó súnmọ́[1] súnmọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè tú gbèdéke Àkókò náà jáde.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ kò sì sunkún!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAfọ́nú-fọ́ra ni yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).