القمر

Al-Qamar

Sūrah 54 · ti Mọkkah · āyah 55 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 37

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: “Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí).”[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn. [1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú[1] wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(al-Ƙur’ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniOjú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Èyí ni ọjọ́ ìṣòro.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBáwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí wọ́n ń wí pé: “Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniGbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.