النازعات
An-Nazi'at
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOhun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOjú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì fi àmì tó tóbi hàn án.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
- Abu Rahimah Mikael Aykyunidájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNíbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.