عبس
'Abasa
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà[1]
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí pé afọ́jú wá bá a.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniòun ni ìwọ tẹ́tí sí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó sì ń páyà (Allāhu),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniìwọ kò sì kọbi ara sí i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ọgbà tó kún fún igi,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.