التكوير

At-Takwir

Sūrah 81 · ti Mọkkah · āyah 29 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 7

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunialágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ kúkú rí i nínú òfurufú kedere.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAl-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.