الإنفطار

Al-Infitar

Sūrah 82 · ti Mọkkah · āyah 19 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 82

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.