المطففين

Al-Mutaffifin

Sūrah 83 · ti Mọkkah · āyah 36 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 86

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈgbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,[1] wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuninígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniní Ọjọ́ ńlá kan?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniTẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?