الإنشقاق

Al-Inshiqaq

Sūrah 84 · ti Mọkkah · āyah 25 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 83

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀[1] -
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunió máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniláìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,[1]
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniláìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniBẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniMo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin[1] ń bẹ fún wọn.