البروج
Al-Buruj
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÒun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniSíbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunití ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.